ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 2/00 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 14
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 21
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 28
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 6
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
km 2/00 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 14

Orin 113

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ táa mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Ṣàtúnyẹ̀wò “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tuntun fún Ọjọ́ Àpéjọ Àkànṣe.”

15 min: “‘Wàásù Ọ̀rọ̀ Náà ní Kánjúkánjú.’” Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi àlàyé kún un láti inú ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 170. Dábàá díẹ̀ tó gbéṣẹ́ nípa bí a ṣe lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìwàásù wa nígbà ẹ̀rùn.

20 min: “Báa Ṣe Lè Lánìímọ́ Ìbánifèròwérò.” Àsọyé àti àṣefihàn. Ṣàlàyé ìdí tí lílánìímọ́ ìbánifèròwérò fi ṣe pàtàkì gidigidi nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti bí a ṣe lè kọ́ ọ. Jẹ́ kí akéde méjì tó dáńgájíá jíròrò bí a ṣe lè múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ nípa títẹ̀lé àwọn ìgbésẹ̀ tí a ṣàlàyé ní ìpínrọ̀ 3 nínú àpilẹ̀kọ náà, lẹ́yìn náà, kí wọ́n ṣàṣefihàn ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ tí wọ́n múra.

Orin 182 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 21

Orin 17

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.

15 min: “Gbogbo Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run Ni Yóò Ní Ìmúṣẹ!” Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣàlàyé àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ díẹ̀ tó fi ìjẹ́pàtàkì àkókò wa hàn, látinú ìwé tuntun yìí.

20 min: “Kí Ló Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Dúró Gbọn-in Nínú Ìgbàgbọ́?” Àsọyé ni kí ó jẹ́, alàgbà ni kó sì sọ ọ́. Àwọn àkókò líle koko là ń gbé, gbogbo wa la sì nílò ìrànwọ́ lọ́nà kan tàbí òmíràn. Ṣàtúnyẹ̀wò ohun tí àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ lè ṣe láti fún àwọn tí wọ́n ní àwọn ìṣòro tí ń múni rẹ̀wẹ̀sì lókun. (Wo àkọlé kékeré tó sọ pé, “Ṣíṣolùṣọ́-Àgùtàn tí Ń Gbéniró,” nínú Ilé-Ìṣọ́nà, September 15, 1993, ojú ìwé 22 àti 23.) Ṣàlàyé báa ṣe lè máa fúnra wa níṣìírí lọ́nà tí yóò fẹ́sẹ̀ wa múlẹ̀ nípa tẹ̀mí.—Róòmù 1:11, 12.

Orin 82 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 28

Orin 46

10  min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Rán gbogbo akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù February sílẹ̀. Ní ṣókí, ṣàtúnyẹ̀wò “Ọ̀nà Mẹ́rin Tó Rọrùn” tí a lè gbà lo àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú wa láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò, tí a ṣàlàyé ní ojú ìwé 4 nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa toṣù tó kọjá. Ṣàṣefihàn bí a ṣe lè lo ìwé àṣàrò kúkúrú Aye Titun alalaafia láti nasẹ̀ ìwé Ìmọ̀. Lẹ́yìn tí o bá béèrè ìbéèrè tó wà ní ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ nínú ìwé àṣàrò kúkúrú náà, ka ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ lójú ìwé 3, àti Sáàmù 37:29. Bí onílé bá fìfẹ́ hàn, ṣí ìwé Ìmọ̀ sí ojú ìwé 5, ka ohun tó wà nínú àpótí níbẹ̀, kí o sì fi ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ ẹni náà. Lóṣù yìí, kí gbogbo akéde sapá lákànṣe láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé ní àfikún sí ti tẹ́lẹ̀.

5 min: Àpótí Ìbéèrè. Àsọyé ni kí ó jẹ́, alàgbà ni kó sì sọ ọ́.

12 min: Mímọrírì Iṣẹ́ Àwọn Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn. Alàgbà ni kó sọ àsọyé yìí, kó gbé e ka àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti November 1995. Àwọn Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tó wà lẹ́nu iṣẹ́ báyìí ní àgbègbè ẹ̀ka Nàìjíríà ti ṣètìlẹyìn fún kíkọ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó lé ọgbọ̀n [530] Gbọ̀ngàn Ìjọba, ṣíṣàtúnṣe wọn, àti títọ́jú wọn. Iṣẹ́ púpọ̀ ṣì wà láti ṣe. Ṣàlàyé iṣẹ́ àwọn ìgbìmọ̀ ẹlẹ́kùnjẹkùn, sì ta àwọn ará jí láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ṣàlàyé àwọn tó lè tóótun gẹ́gẹ́ bí olùyọ̀ǹda ara ẹni, kí o rọ àwọn èèyàn púpọ̀ sí i láti yọ̀ǹda ara wọn. (Wo àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti April 1998, ìpínrọ̀ 12 sí 14.) Fọ̀rọ̀ wá àwọn kan tó ti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba lẹ́nu wò, kí wọ́n sì sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe láyọ̀ tó.—Wo Ilé Ìṣọ́ June 1, 1999, ojú ìwé 18 àti 19, ìpínrọ̀ 15 sí 16.

18 min: “Fífi Ìgbàgbọ́ Tó Lágbára Wàásù Ìhìn Rere Náà.” Fi ìṣẹ́jú méjì sí mẹ́ta sọ ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ń wúni lórí látinú àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà àti látinú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ táa tọ́ka sí, àtàwọn èyí táa fà yọ ní ìpínrọ̀ 1 àti 2. Lẹ́yìn náà, kóo wá jíròrò ìpínrọ̀ 3 sí 12 lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

Orin 61 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 6

Orin 116

5 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.

10 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

15 min: “Fiyè sí Bí O Ṣe Ń Fetí Sílẹ̀.” Kí olórí ìdílé kan bá ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀ jíròrò nípa ohun tí wọ́n lè ṣe láti túbọ̀ máa jàǹfààní ní kíkún látinú àwọn ìpàdé ìjọ, àwọn àpéjọ, àti àwọn àpéjọpọ̀. Ó ronú pé gbogbo mẹ́ńbà ìdílé òun lè túbọ̀ máa pọkàn pọ̀. Wọ́n ṣàyẹ̀wò àwọn àbá tí a pèsè àti bí wọ́n ṣe lè fi ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sílò, títí kan bí ó ti dáa pé kí wọ́n máa jíròrò àwọn nǹkan tí wọ́n ń kọ́ síwájú sí i. Wọ́n jíròrò bí wọ́n ṣe lè ṣiṣẹ́ lórí ìpinnu wọn láti má ṣe pa ìpàdé kankan jẹ, kí wọ́n má sì pàdánù apá kankan nínú àpéjọpọ̀ tàbí àpéjọ níwọ̀n ìgbà tí kì í bá ṣe pé ó kọjá agbára wọn.

15 min: “Fífi Ìgbàgbọ́ Tó Lágbára Wàásù Ìhìn Rere Náà.” Lẹ́yìn àtúnyẹ̀wò ráńpẹ́ nípa ohun táa jíròrò lọ́sẹ̀ tó kọ́ja nínú ìpínrọ̀ méjìlá àkọ́kọ́ tó wà nínú àkìbọnú náà, jíròrò ìpínrọ̀ 13 sí 24 lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Lo ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ táa fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ, àtàwọn táa tọ́ka sí.

Orin 186 àti àdúrà ìparí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́