ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 7/01 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 9
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 16
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 23
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 30
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 6
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 7/01 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 9

Orin 4

8 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ táa mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.

17 min: Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn March. Àsọyé àti ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò tí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn yóò bójú tó. Sọ̀rọ̀ nípa ìròyìn iṣẹ́ ìsìn March ti orílẹ̀-èdè yìí àti ti ìjọ yín. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu onírúurú àwọn akéde tí wọ́n sapá lárà ọ̀tọ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lóṣù yẹn. Jẹ́ kí wọ́n sọ nípa ìdùnnú tí wọ́n ní nítorí kíkópa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣe láti máa báa lọ ní kíkún fún iṣẹ́ pẹrẹu lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́.

20 min: “Ǹjẹ́ O Lè Sìn Níbi Tí Àìní Gbé Pọ̀?”a Fi àwọn ìrírí tó ń fúnni níṣìírí tí àwọn akéde inú ìjọ yín ní ní ìpínlẹ̀ tó wà ní àdádó tàbí ní ìpínlẹ̀ tí ẹ kì í sábàá ṣe kún un.—Wo ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 112 àti 113.

Orin 42 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 16

Orin 10

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó.

15 min: Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Ṣírò Ohun Tí Iṣẹ́ Ìgbésí Ayé Yín Yóò Ná-an Yín. Bàbá kan àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tàbí ọmọ rẹ̀ obìnrin tó jẹ́ ọ̀dọ́langba tọ alàgbà kan lọ tó ní ìrírí gidi nípa iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́. Lẹ́yìn tí ọ̀dọ́ náà ronú jinlẹ̀ lórí apá Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ti ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́yìn nípa yíyan iṣẹ́ ìgbésí ayé, ó ń ronú gidigidi lórí bíbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà déédéé ṣùgbọ́n kò mọ bó ṣe máa lè gbọ́ bùkátà ara rẹ̀. Alàgbà tẹnu mọ́ ọn pé ó yẹ kó ní èrò tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. (Ilé Ìṣọ́, September 1, 1999, ojú ìwé 11, ìpínrọ̀ 13) Ó bọ́gbọ́n mu kéèyàn gba àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan kí èèyàn lè lágbára láti gbọ́ bùkátà ara rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ti ṣe dáadáa nípa wíwulẹ̀ kọ́ iṣẹ́ gidi kan tí kò gba àkókò àti owó púpọ̀. (Ilé Ìṣọ́, February 1, 1996, ojú ìwé 14; Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè, ojú ìwé 178) Wọ́n jọ jíròrò Jí!, March 8, 1996, ojú ìwé 9 sí 11 àti àwọn àbá mélòó kan tó wúlò fún rírí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tó bójú mu tàbí dídá a sílẹ̀.

20 min: Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ta Ni Wọ́n? Kí Ni Wọ́n Gbà Gbọ́? Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ àti àṣefihàn. Ṣàyẹ̀wò ìwé pẹlẹbẹ yìí kí o sì jíròrò bí a ṣe lè lò ó láti fi ṣàlàyé nípa wa àti nípa iṣẹ́ wa fún àwọn ẹlòmíràn. Ó sọ ẹni tí a jẹ́ (ojú ìwé 3 sí 5), ó ṣàlàyé díẹ̀ lára ìtàn wa òde òní àti ìgbòkègbodò wa (ojú ìwé 6 sí 11), ó sọ àwọn ohun tí a gbà gbọ́ tó mú ká yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀sìn yòókù (ojú ìwé 12 sí 14), ó ṣàlàyé ìhìn rere tí a ń wàásù àti bí a ṣe ń wàásù rẹ̀ (ojú ìwé 15 sí 21), ó sọ bí iṣẹ́ wa ṣe ń ṣe àwùjọ láǹfààní (ojú ìwé 22 sí 24), ó sọ bí ètò àjọ wa ṣe rí kárí ayé (ojú ìwé 25 àti 26), ó sì dáhùn àwọn ìbéèrè tí àwọn èèyàn sábà máa ń béèrè nípa wa (ojú ìwé 27 sí 31). Jẹ́ kí a ṣàṣefihàn kan níbi tí akéde kan ti ń lo ìwé pẹlẹbẹ yìí láti dáhùn ọ̀kan nínú àwọn ìbéèrè tó wà lójú ewé 29 tí onílé kan tó ń wádìí béèrè, lẹ́yìn náà, akéde náà wá rọ ẹni náà bó ti wà lẹ́yìn ìwé pẹlẹbẹ náà. Fún gbogbo akéde níṣìírí pé kí wọ́n lo ìwé pẹlẹbẹ náà láti jẹ́ kí àwọn ìbátan wọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí mọ̀ nípa wa, láti mú kí ìfẹ́ tí ẹnì kan fi hàn túbọ̀ pọ̀ sí i nígbà ìpadàbẹ̀wò, kí wọ́n sì fi darí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sínú ètò àjọ yìí.

Orin 50 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 23

Orin 19

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

20 min: “Múra Sílẹ̀ Láti Kẹ́kọ̀ọ́ Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà O!”b Ṣàlàyé ṣókí nípa bí a óò ṣe jàǹfààní nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ ìwé Aísáyà. (Wo orí 1, ìpínrọ̀ 10 sí 12, nínú ìwé Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní.) Fún gbogbo àwùjọ níṣìírí láti máa wá sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ déédéé.

Orin 53 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 30

Orin 22

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù July sílẹ̀.

20 min: Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Lo Ìfòyemọ̀ Láti Wéwèé Ètò Ẹ̀kọ́ Yín. Alàgbà kan bá àwọn òbí kan àtàwọn ọmọ wọn tó jẹ́ ọ̀dọ́langba sọ̀rọ̀ nípa àfikún ìmọ̀ ẹ̀kọ́. Alàgbà náà ṣáájú nínú jíjíròrò Ilé Ìṣọ́, September 1, 1999, ojú ìwé 16 àti 17, ìpínrọ̀ 11 sí 13, ní títẹnumọ́ àwọn ìdí tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún fi ní láti gba ipò iwájú nígbà tí wọ́n bá ń gbé ohun àkọ́múṣe kalẹ̀. (Ilé Ìṣọ́, December 1, 1996, ojú ìwé 18 àti 19, ìpínrọ̀ 13 sí 15) Àwùjọ náà yóò wá ṣàtúnyẹ̀wò ìmọ̀ràn tó wà nínú Jí!, March 8, 1998, ojú ìwé 20 àti 21 tó tẹnu mọ́ ọn pé ó ṣe pàtàkì láti lo ìfòyemọ̀ ní ríronú nípa ire àti ibi tó wà nínú àfikún ìmọ̀ ẹ̀kọ́ àti fífi í mọ sí ohun tí a nílò láti gbọ́ bùkátà ara ẹni bí èèyàn ti ń fi ìtara bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ nìṣó. Gbogbo wọn gbà pé ìmọ̀ràn Jésù pé ká fi ire Ìjọba náà sí ipò kìíní ló ní láti darí àwọn.—Mát. 6:33.

15 min: Ìjíròrò lẹ́tà ti March 23, 2001, Sí Gbogbo Ìjọ ní Nàìjíríà, tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀nà awúrúju tí àwọn èèyàn fi ń wá owó. Kí alàgbà méjì bójú tó o, kí wọ́n sì ṣàlàyé gbogbo ìpínrọ̀ rẹ̀. Kí wọ́n ka ìpínrọ̀ 5, kí wọ́n sì ṣàlàyé rẹ̀.

Orin 57 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 6

Orin 25

15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àpótí Ìbéèrè.

10 min: “Kí Nìdí Tí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Déédéé Nínú Ìdílé Fi Ṣe Pàtàkì Gan-an?” Àsọyé tí alàgbà kan sọ.

20 min: “Má Ṣe Lọ́ Tìkọ̀!”c Bí àkókò bá ti wà tó, sọ àwọn ìrírí tó wà nínú Ilé Ìṣọ́, December 15, 1999, ojú ìwé 25.

Orin 63 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́