ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/01 ojú ìwé 5-6
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọrun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọrun
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 8/01 ojú ìwé 5-6

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọrun

Àtúnyẹ̀wò pípa ìwé dé lórí àkópọ̀ ẹ̀kọ́ tí a kárí nínú àwọn iṣẹ́ àyànfúnni Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọrun fún àwọn ọ̀sẹ̀ May 7 sí August 20, 2001. Lo abala tákàdá ọ̀tọ̀ láti fi kọ ìdáhùn sí púpọ̀ nínú àwọn ìbéèrè náà, bí ó bá ti lè ṣeé ṣe fún ọ tó, ní ìwọ̀n àkókò tí a yàn.

[Àkíyèsí: Lákòókò àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀, Bibeli nìkan ni a lè lò láti dáhùn ìbéèrè èyíkéyìí. Àwọn ìtọ́kasí tí ó tẹ̀ lé àwọn ìbéèrè wà fún ìwádìí fúnra rẹ. Nọ́ḿbà ojú ìwé àti ìpínrọ̀ lè má fara hàn nínú gbogbo àwọn ìtọ́kasí tí a ṣe sí Ilé Ìṣọ́.]

Dáhùn Òtítọ́ tàbí Èké sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tó tẹ̀ lé e yìí:

1. Àdúrà táa sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní Nehemáyà 2:4 jẹ́ àdúrà onígbèkúútà tí Nehemáyà gbà nígbà tọ́ràn ti bọ́ sórí tán. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w86-YR 6/1 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 8.]

2. A túmọ̀ ọ̀rọ̀ náà, “ìjọ” láti inú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, ek·kle·siʹa, nínú èyí tí àwọn èrò tó ṣe pàtàkì níbẹ̀ jẹ́ ẹ̀mí ìṣọ̀kan àti ìranra-ẹni-lọ́wọ́. [w99-YR 5/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 4]

3. Ẹ̀tọ́ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù jẹ́ kí ó lè gbèjà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lábẹ́ òfin, ẹ̀tọ́ yìí ló sì lò tó fi mú ìhìn rere náà lọ bá aláṣẹ gíga jù lọ ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù. (Ìṣe 16:37-40; 25:11, 12) [w99-YR 5/15 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 2]

4. Ní sáà àkókò tí Jóòbù gbé ayé, òun nìkan ni ènìyàn tó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. (Jóòbù 1:8) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w92-YR 8/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 3 àti 4.]

5. Nítorí pé Sọ́ọ̀lù, tàbí Pọ́ọ̀lù fi pípa àgọ́ gbọ́ bùkátà ara rẹ̀, ìyẹn fi hàn pé látinú ìdílé tálákà ló ti wá. (Ìṣe 18:2, 3) [w99-YR 5/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 1]

6. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì dẹ́ṣẹ̀ ńlá, Jèhófà lè sọ nípa rẹ̀ pé ó “fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ̀ tọ̀ mí lẹ́yìn” nítorí pé Dáfídì ronú pìwà dà, ó sì ní àwọn ànímọ́ rere. (1 Ọba 14:8) [w99-YR 6/15 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 4]

7. Bí kì í bá í ṣe pé ohun tí a ṣèlérí kò bá Ìwé Mímọ́ mu, a gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti mú ìlérí wa ṣẹ kódà bí a bá wá rí i lẹ́yìn náà pé ohun tí a ṣèlérí náà kò rọrùn láti ṣe. (Sm. 15:4) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w89-YR 9/15 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 6.]

8. Sáàmù 22:1 fi hàn pé nígbà kan tí Dáfídì wà lábẹ́ ìnira, ó sọ ìgbàgbọ́ rẹ̀ nù fúngbà díẹ̀. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w86-YR 8/15 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 19.]

9. Ẹ́sítérì fi hàn pé ìmẹ̀tọ́mọ̀wà níye lórí nípa ṣíṣàìbéèrè àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tàbí aṣọ olówó ńlá kí ó tó lè wọlé tọ ọba lọ. Ńṣe ló jẹ́ kí ẹni tó jẹ́ nínú lọ́hùn-ún, pẹ̀lú “ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ti ìwà tútù,” mú òun jèrè ojú rere ọba. (Ẹ́sít. 2:15; 1 Pét. 3:1-5) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w86-E 3/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 10.]

10. Àní bí àwọn olùṣe búburú tiẹ̀ ní aásìkí, a kò gbọ́dọ̀ ṣe ìlara kí á sì máa gbìyànjú láti fara wé wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ní láti “dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Jèhófà,” ká má ṣe ṣe àríwísí, ṣùgbọ́n dípò ìyẹn, ká pa rọ́rọ́ ká sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀ láti gbèjà wa nígbà tó bá tó àkókò lójú rẹ̀. (Sm. 37:5, 7) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w86-YR 8/15 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 16.]

Dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí:

11. Báwo ni Ẹ́sírà àti àwọn tó ń ràn án lọ́wọ́ ṣe “fi ìtumọ̀ sí” Òfin? (Neh. 8:8) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w86-YR 6/1 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 4.]

12. Kí ló ń mú “ìdùnnú Jèhófà” wá? (Neh. 8:10) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w86-YR 6/1 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 9.]

13. Èé ṣe tí a fi súre fún ‘àwọn tó fínnú-fíndọ̀ yọ̀ǹda ara wọn láti máa gbé ní Jerúsálẹ́mù?’ (Neh. 11:2) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w86-YR 6/1 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 12.]

14. Kí nìdí tí Ẹ́sítérì fi lọ́ tìkọ̀ láti sọ èrò ọkàn rẹ̀ gan-an fún ọba? (Ẹ́sítérì 5:6-8) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w86-E 3/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 18.]

15. Nígbà ayé Jóòbù, àríyànjiyàn ńláǹlà wo ni Sátánì gbé dìde? (Jóòbù 1:6–2:8) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w94-YR 11/15 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 5.]

16. Kí nìdí tí ìmọ̀ràn Élífásì fi mú ọkàn Jóòbù gbọgbẹ́ tí kò sì fún un níṣìírí? (Jóòbù 21:34; 22:2, 3) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w95-YR 2/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 5 àti 6.]

17. Kí ni sáàmù? [w86-YR 8/15 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 1]

18. Kí ni “nǹkan òfìfo” tí àwọn orílẹ̀-èdè ‘ń sọ lábẹ́lẹ̀’ gẹ́gẹ́ bó ṣe wà ní Sáàmù 2:1? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w86-YR 8/15 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 5.]

19. Ẹ̀kọ́ gidi wo nípa àìṣojúsàájú la lè rí kọ́ lára iṣẹ́ òjíṣẹ́ Fílípì tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ará Samáríà àti ìjòyè tó jẹ́ ará Etiópíà? (Ìṣe 8:6-13, 26-39) [w99-YR 7/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 2]

20. Báwo ni Jóòbù ṣe ṣàpèjúwe ìdánilójú tó ní pé Ọlọ́run lè pé òun jáde kúrò nínú sàréè, tí ó wò pé ó jẹ́ ibi ìlùmọ́ kan kúrò lọ́wọ́ àwọn ìṣòro òun? (Jóòbù 14:7, 13-15) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w00-YR 5/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 7 sí ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 1.]

Pèsè ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn tó yẹ kó wà ní àlàfo inú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tó tẹ̀ lé e yìí:

21. Ẹ́sítérì 8:17 sọ pé àwọn èèyàn náà “ń polongo ara wọn ní Júù”; bákan náà lónìí, “ __________________________ ti “àwọn àgùntàn mìíràn” ti dúró ti __________________________. (Ìṣí. 7:9; Jòh. 10:16; Sek. 8:23) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w86-E 3/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 14.]

22. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gẹ́gẹ́ bí Ìṣe 1:7 ṣe fi hàn, Jèhófà kì í fi __________________________ ṣeré rárá, ọjọ́ ìjíhìn rẹ̀ yóò dé gẹ́gẹ́ bí __________________________, nígbà tí àwọn ènìyàn kò retí rẹ̀. (2 Pét. 3:10) [w99-YR 6/1 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 2 àti 3]

23. Jèhófà ń __________________________ àwọn ènìyàn rẹ̀ olùfọkànsìn láti jẹ́rìí __________________________, kódà bí àdánwò bá ti sọ wọ́n di __________________________ bí òkú. (Jóòbù 26:5) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w94-YR 11/15 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 1.]

24. Àwọn ohun tí ń mú kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó dán mọ́rán ṣeé ṣe ni níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ẹni, fífọkàn tánni, àti kí tọ̀tún tòsì gbọ́ra wọn yé. Àwọn ànímọ́ wọ̀nyí máa ń yọjú nígbà tí a bá fojú àjọṣepọ̀ __________________________ wo ìgbéyàwó tí a sì ti __________________________ tán láti mú kí ó ṣiṣẹ́ yọrí. [w99-YR 7/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 3]

25. Ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe tó jẹ́ èyí tó dára lè ràn wá lọ́wọ́ láti fi àwọn ohun tí a ń béèrè ní ti ìwà rere àti tẹ̀mí __________________________, ó sì lè tipa bẹ́ẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti fi __________________________ wa sin Jèhófà. [w99-YR 8/1 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 4]

Mú ìdáhùn tó tọ̀nà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tó tẹ̀ lé e yìí:

26. Jíjókòó tí Módékáì “ń jókòó ní ẹnubodè ọba” fi hàn pé ó jẹ́ (ẹ̀ṣọ́ ọba; ọ̀kan lára àwọn ìjòyè Ahasuwérúsì Ọba; ńṣe ló ń dúró láti bá ọba sọ̀rọ̀). (Ẹ́sítérì 2:19, 20) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w86-E 3/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 9.]

27. Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà ní Jóòbù 19:25-27, Jóòbù fi ìgbàgbọ́ hàn pé òun yóò “rí Ọlọ́run” ní ti pé (a ó fi ìran kan hàn án; a óò jí i dìde sí ìyè ti ọ̀run; a óò ṣí ojú òye rẹ̀ sí òtítọ́ nípa Jèhófà). [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w94-YR 11/15 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 17.]

28. Jóòbù jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ ní ti (ìgbàgbọ́; inú rere; ìfaradà). (Jóòbù 42:10-17; Ják. 5:11) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w94-YR 11/15 ojú ìwé 23 àti 24 ìpínrọ̀ 13 àti 14.]

29. Apá (mẹ́ta; mẹ́fà; márùn-ún) la pín ìwé Sáàmù sí [w86-YR 8/15 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 2]

30. A ń béèrè (ìfaradà; ìfẹ́; ìgbàgbọ́) láti dúró de Ọlọ́run láti gbé ìgbésẹ̀ nítorí wa. [w86- YR 10/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 15]

So àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó tẹ̀ lé e yìí mọ́ èyí tó bá a mu lára àwọn gbólóhùn tí a tò sí ìsàlẹ̀ yìí:

Neh. 3:5; Sm. 12:2; 19:7; 37:23, 24; 2 Pét. 3:15

31. Kò yẹ ká ronú pé ipò wa ti ga kọjá ká máa fi gbogbo ara ṣiṣẹ́, kàkà bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ múra tán láti fara ṣiṣẹ́, kì í ṣe pé ká wá máa gbéra ga, ká máa yẹra fún iṣẹ́. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w86-YR 6/1 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 12 àti 19.]

32. Kristẹni kan lè “ṣubú” ní ti pé ó ní ìjákulẹ̀ tàbí pé àwọn àyídà òfin kó wàhálà bá a tàbí pé ọrọ̀ ajé rẹ̀ dẹnu kọlẹ̀, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrànwọ́ ẹ̀mí Ọlọ́run àtàwọn olùjọsìn Rẹ̀ onífẹ̀ẹ́, a kì yóò ‘gbé e ṣánlẹ̀’ nípa tẹ̀mí pátápátá. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w86-YR 11/1 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 14.]

33. Sùúrù Ọlọ́run tí mú kó ṣeé ṣe fún wa láti mọ ète rẹ̀ àti láti mú ìgbésí ayé wa bá a mu, ká lè rí ìbùkún tó ti ṣèlérí gbà. [w99-YR 6/1 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 4]

34. Báa bá fẹ́ ìbádọ́rẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ dénúdénú láìsí àgàbàgebè. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w89-YR 9/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 7.]

35. Ṣíṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run ń ta ọkàn jí, ó sì ń fi kún ayọ̀ ẹni. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w00-YR 10/1 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 4.]

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́