Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 13
Orin 30
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ táa mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Fún olúkúlùkù níṣìírí pé kí wọ́n wo fídíò The New World Society in Action láti múra sílẹ̀ fún ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí yóò wáyé ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ní ọ̀sẹ̀ August 27.
17 min: “Ṣé O Fẹ́ Ṣe Púpọ̀ Sí I?”a Fi ìmọ̀ràn kún un nípa bí ẹ ṣe lè ṣe púpọ̀ sí i láti jẹ́rìí fún àwọn èèyàn ní ìpínlẹ̀ yín. Sọ̀rọ̀ ní ṣókí lórí Ilé Ìṣọ́, June 15, 1997, ojú ìwé 26 sí 29.
18 min: “Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Láti Wéwèé Kí Wọ́n sì Lo Àkókò Ìsinmi Wọn Lọ́nà Ọgbọ́n.”b Alàgbà ni kí ó bójú tó o.
Orin 221 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 20
Orin 33
8 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó.
15 min: “‘Ìran Àpéwò ní Gbọ̀ngàn Ìwòran’ Ni Yín!”c Sọ nípa àwọn ohun kan tó ṣẹlẹ̀ ládùúgbò yín tó mú káwọn èèyàn sọ ọ̀rọ̀ rere nípa iṣẹ́ tàbí nípa ìwà àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.—Wo Ilé Ìṣọ́, March 15, 1998, ojú ìwé 10, àti January 15, 1999, ojú ìwé 32.
22 min: “Ìwà Rere La Fi Ń Dá Àwọn Èèyàn Tó Ń Fọkàn Sin Ọlọ́run Mọ̀.” Kí Alàgbà kan sọ àsọyé oníṣẹ̀ẹ́jú márùn-ún lórí ìpínrọ̀ 1 sí 5. Lẹ́yìn náà, kí ó bá alàgbà mìíràn àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan jíròrò ìpínrọ̀ yòókù nínú àpilẹ̀kọ náà lórí pèpéle. Wọ́n sọ̀rọ̀ nípa béèyàn ṣe lè borí àwọn ìwà àìbìkítà fún ẹlòmíràn tó lè tàbùkù ìpàdé wa, tó sì lè dín àǹfààní tí a ń rí níbẹ̀ kù. Wọ́n ṣàlàyé nípa bí ìbákẹ́gbẹ́ láàárín ara wa ṣe ń fúnni níṣìírí ní tòótọ́ nígbà tí a bá ń fìfẹ́ bìkítà nípa ọ̀ràn tó kan àwọn ẹlòmíràn.—Fílí. 2:4.
Orin 72 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 27
Orin 40
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù August sílẹ̀. Ní ṣókí, dámọ̀ràn ọ̀nà kan tàbí méjì tí a lè gbà fi ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye lọni lóde ẹ̀rí lóṣù September.—Wo àwọn àpẹẹrẹ nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti June 1995, ojú ìwé 4.
15 min: “Fi Fàájì Mọ sí Àyè Tó Yẹ Kó Wà.” Olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ kan ń bá tọkọtaya kan fọ̀rọ̀ wérọ̀ lẹ́yìn ìpàdé. Ó fi pẹ̀lẹ́tù sọ fún wọn pé lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí, òun kò rí wọn kí wọ́n lọ sí òde ẹ̀rí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò wá sí àwọn ìpàdé òpin ọ̀sẹ̀. Tọkọtaya ọ̀hún sọ pé àwọn ibi ìgbéyàwó àti àwọn àpèjẹ táwọn lọ ni kò jẹ́ kí àwọn ráyè. Alàgbà náà ṣàyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí, ó sì ran tọkọtaya náà lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ̀ pé àwọn nǹkan tẹ̀mí ló yẹ kí ó máa gba ipò kìíní nígbà gbogbo. Wọ́n dúpẹ́ fún ìránnilétí dáadáa yìí. Wọ́n gbà pé àwọn yóò ṣètò kó lè jẹ́ pé lọ́jọ́ iwájú, ohun tó yẹ kó ṣáájú làwọn á fi ṣáájú.—Wo Ilé Ìṣọ́, October 1, 2000, ojú ìwé 19 àti 20.
20 min: “Ṣíṣàyẹ̀wò Ìtàn Inú Fídíò The New World Society in Action.” Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú àwùjọ. Ní oṣù October, a óò ṣàyẹ̀wò fídíò United by Divine Teaching. Ní àfidípò, sọ̀rọ̀ lórí “Kòṣeémánìí Lètò Àjọ Jèhófà.” Kí alàgbà sọ àsọyé yìí táa gbé ka Ilé Ìṣọ́, January 1, 2000, ojú ìwé 30 àti 31.
Orin 74 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 3
Orin 80
8 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
17 min: “Báwo Ni Ìbákẹ́gbẹ́ Kristẹni Ti Ṣe Pàtàkì Tó?”d Fi àlàyé kún un látinú ọ̀rọ̀ tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí náà, “Nípasẹ̀ Ìjọ,” nínú Ilé-Ìṣọ́nà, January 15, 1996, ojú ìwé 22.
20 min: Fífèsì Àwọn Ọ̀rọ̀ Tó Lè Bẹ́gi Dínà Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀. Àlàyé àti àwọn àṣefihàn. Nígbà tí àwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀ tàbí tí wọ́n bá béèrè ìbéèrè tí a kò retí rẹ̀ lóde ẹ̀rí, ó yẹ ká sakun láti fèsì dípò tí a óò fi yí kókó ọ̀rọ̀ ọ̀hún padà tàbí dípò fífòpin sí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ náà. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìwé kékeré náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, yóò wúlò fún èyí. Mẹ́nu kan àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn èèyàn sábà máa ń sọ, kí o sì jẹ́ kí àwọn akéde ṣàṣefihàn bí a ṣe lè fi àlàyé inú ìwé kékeré náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, fèsì. Fún gbogbo akéde níṣìírí pé kí wọ́n máa lo ìwé kékeré náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, nígbà tí àwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀ tàbí tí wọ́n bá béèrè ìbéèrè tí a kò retí rẹ̀ lóde ẹ̀rí.
Orin 121 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.