Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí la óò gbé yẹ̀ wò nínú àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní December 29, 2003. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò darí àtúnyẹ̀wò yìí fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, èyí tá a gbé ka àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe ní ọ̀sẹ̀ November 3 sí December 29, 2003. [Àkíyèsí: Níbi tí a kò bá ti tọ́ka sí ibi tí a ti mú ìdáhùn jáde lẹ́yìn ìbéèrè kan, o ní láti ṣe ìwádìí fúnra rẹ láti wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè náà.—Wo ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 36 àti 37.]
ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ
1. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti máa lo Bíbélì lóde ẹ̀rí? [be-YR ojú ìwé 145, ìpínrọ̀ 2, àpótí]
2. Báwo ni ipò tó yí ọ̀rọ̀ kan ká ṣe kan bó ṣe yẹ ká nasẹ̀ Ìwé Mímọ́ kan? [be-YR ojú ìwé 149]
3. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì ká máa tẹnu mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tó yẹ nígbà tá a bá ń ka ẹsẹ Bíbélì kan, báwo la sì ṣe lè ṣe èyí? [be-YR ojú ìwé 151, ìpínrọ̀ 2, àpótí]
4. Báwo la ṣe lè lo ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù láti “fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́” nígbà tá a bá ń kọ́ àwọn ẹlòmíràn, kí sì nìdí tí èyí fi ṣe pàtàkì? (2 Tím. 2:15) [be-YR ojú ìwé 153, ìpínrọ̀ 2, àpótí]
5. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe “fèrò-wérò láti inú Ìwé Mímọ́”? (Ìṣe 17:2, 3) [be-YR ojú ìwé 155, ìpínrọ̀ 4 àti 5]
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ
6. Nígbà tá a bá ń lo Bíbélì ohun èlò ìṣèwádìí wa tó gba iwájú jù lọ láti fi múra àwíyé sílẹ̀, kí nìdí tó fi ṣàǹfààní (1) láti gbé ohun tí ó fa ẹsẹ yẹn yẹ̀ wò, (2) láti yẹ àwọn atọ́ka etí ìwé wò àti (3) láti fi atọ́ka ọ̀rọ̀ Bíbélì wá ọ̀rọ̀? [be-YR ojú ìwé 34, ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 35 ìpínrọ̀ 2]
7. Báwo la ṣe lè jẹ́ adúróṣinṣin, ta sì ló yẹ ká jẹ́ adúróṣinṣin sí? [w01-YR 10/1 ojú ìwé 22 àti 23]
8. Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà: “Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí dá ènìyàn ní àwòrán rẹ̀, àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a; akọ àti abo ni ó dá wọn.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) [w01-YR 12/1 ojú ìwé 4 ìpínrọ̀ 2]
9. Kí làwọn ohun tó yẹ ká fi sọ́kàn nígbà tá a bá fẹ́ pinnu àwọn kókó tá a máa lò lẹ́yìn tí a ti ṣe ìwádìí lórí ọ̀rọ̀ tá a yàn fún wa láti sọ? [be-YR ojú ìwé 38]
10. Báwo ni ọ̀rọ̀ Jésù nípa “àwọn ọjọ́ Nóà” ṣe bá ipò wa mu lónìí? (Mát. 24:37) [w01-YR 11/15 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 3 àti 4]
BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀
11. Báwo ni lẹ́tà Pọ́ọ̀lù sí Fílémónì ṣe fi hàn pé iṣẹ́ tá a gbé lé Kristẹni kan lọ́wọ́ ni láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè di Kristẹni, kì í ṣe láti gbé ìbárẹ́ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà lárugẹ? (Fílém. 12)
12. Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín kí ẹnì kan ‘sú lọ,’ kó ‘lọ́ kúrò’ àti kó ‘yẹsẹ̀’? (Héb. 2:1; 3:12; 6:6) [w99-YR 7/15 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 12; w86-E 6/1 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 16 àti 17; w81-YR 6/1 ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 8]
13. Báwo la ṣe lè yàgò fún sísọ ọ̀rọ̀ náà “bí Jèhófà bá fẹ́” di ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì? (Ják. 4:15) [cj-E ojú ìwé 171, ìpínrọ̀ 1 àti 2]
14. Kí ló túmọ̀ sí láti ‘dúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà, ká sì fi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí’ àti pé báwo la ṣe lè ṣe é? (2 Pét. 3:12) [w97-YR 9/1 ojú ìwé 19 àti 20]
15. Ìmọ̀ràn pàtàkì wo ló wà fún àwa Kristẹni lónìí látinú iṣẹ́ tí a rán sáwọn ìjọ méje tí a dárúkọ nínú Ìṣípayá orí 2 àti orí 3? (Ìṣí. 2:4, 5, 10, 14, 20; 3:3, 10, 11, 17, 19)