Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 10
Orin 49
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù April sílẹ̀. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ April 15 àti Jí! April-June. (Lo àbá kẹta fún Jí! April-June.) Nínú àṣefihàn kan, ní kí akéde tún fún onílé tó fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ tó jinlẹ̀ sí ọ̀rọ̀ Bíbélì ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni.
15 min: “Bá Ò Ṣe Ní Jẹ́ Kí Ìtara Wa Dín Kù.”a Fi àlàyé kún un látinú Ilé Ìṣọ́ June 15, 2002, ojú ìwé 14, ìpínrọ̀ 13.
20 min: “Ṣó O Lè Tún Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Rẹ Ṣe?”b Mú un bá àdúgbò yín mu. Mẹ́nu ba ìṣètò tí ìjọ ti ṣe láti wàásù ní ìrọ̀lẹ́.
Orin 13 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 17
Orin 104
15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwùjọ létí nípa ìṣètò tí ìjọ ṣe fún àkànṣe àsọyé. Gba àwọn ará níyànjú láti máa lo èèpo ẹ̀yìn Ilé Ìṣọ́ April 1 láti pe àwọn tó ti máa ń wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tẹ́lẹ̀, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àti àwọn míì tó lè nífẹ̀ẹ́ sí i, wá síbi Ìrántí Ikú Kristi. Sọ ìrírí méjì tàbí mẹ́ta ní ráńpẹ́ nípa báwọn ara ṣe ń fi Ilé Ìṣọ́ yìí pe àwọn èèyàn wá síbi àkànṣe àsọyé.
12 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
18 min: “Báwo La Ṣe Lè Kó Ẹ̀dùn Ọkàn Bá Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run, Nígbà Tí Kì Í Ṣe Ẹni Gidi Kan?” Àsọyé tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ May 15, 2004, ojú ìwé 29 sí 30.
Orin 138 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 24
Orin 66
15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́. Jálẹ̀ oṣù May, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la ó ṣì máa lò. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ May 1 àti Jí! April-June. (Lo àbá kẹrin fún Jí! April-June.) Lẹ́yìn àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, mẹ́nu ba àwọn àpilẹ̀kọ mìíràn nínú ìtẹ̀jáde náà tó lè fa àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mọ́ra.
30 min: “Àpéjọ Àgbègbè ‘Ìdáǹdè Kù sí Dẹ̀dẹ̀!’ ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ọdún 2006.”c Akọ̀wé ìjọ ni kó bójú tó o. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti jíròrò ìpínrọ̀ 1, ka lẹ́tà April 1, 2006 tí ọ́fíìsì fi sọ ibi tí ìjọ yín ti máa ṣe àpéjọ náà. Gba àwùjọ níyànjú láti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò láti lọ sí àpéjọ náà ní báyìí.
Orin 48 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 1
Orin 211
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù April sílẹ̀. Jíròrò àpótí tó dá lórí “Ǹjẹ́ O Ti Fìgbà Kan Rí Béèrè Ẹni Tó Tún Máa Nífẹ̀ẹ́ sí I?, èyí tó wà lójú ìwé 7.”
15 min: “Fi Hàn Pé Ọ̀rọ̀ Àwọn Èèyàn Jẹ Ọ́ Lógún—Nípa Wíwo Ojú Wọn.”d Fi àṣefihàn ráńpẹ́ kún un nínú èyí tí akéde kan ti jẹ́ kójú òun àti ẹnì kan ṣe mẹ́rin níbi táwọn èèyàn sábà máa ń pọ̀ sí, èyí tó mú kó fọ̀rọ̀ lọ ẹni náà kó tó wá jẹ́rìí fún un.
20 min: Máa Ṣàṣàrò Lórí Iṣẹ́ Jèhófà. (Sm. 77:12) Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tó dá lórí ìwé ọdọọdún wa ti 2006, ìyẹn 2006 Yearbook. Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn kókó afúnniníṣìírí tó wà nínú lẹ́tà tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí kọ sí wa. (A fi ẹ̀dá kan lédè Yorùbá sínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí) Níbi tó bá ti ṣeé ṣe, kẹ́ ẹ jíròrò kókó tó wà lábẹ́ àkòrí náà, “Bible Translation” [Iṣẹ́ Ìtumọ̀ Bíbélì]. (ojú ìwé 10 sí 11) Sọ àwọn ìrírí àtàwọn nǹkan pàtàkì tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún tó kọjá. (ojú ìwé 6 sí 64) Ní kí àwùjọ sọ ohun tí wọ́n rí nínú ìwé ọdọọdún wa náà, tó dùn mọ́ wọn nínú. Gba àwùjọ níyànjú láti fi ìsọfúnni tó wà nínú ẹ̀ ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ mọyì ètò Jèhófà.
Orin 82 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.