ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 6/06 ojú ìwé 3
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
km 6/06 ojú ìwé 3

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí la óò gbé yẹ̀ wò nígbà àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní June 26, 2006. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò darí àtúnyẹ̀wò yìí fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, èyí tó dá lórí àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe lọ́sẹ̀ May 1 sí June 26, 2006. [Àkíyèsí: Níbi tí a kò bá ti sọ ibi tí a ti mú ìdáhùn jáde lẹ́yìn ìbéèrè kan, o ní láti ṣe ìwádìí láti wá ìdáhùn sí ìbéèrè náà.—Wo ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 36 àti 37.]

ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ

1. Kí ló ń jẹ́ iyípadà ohùn nínú ọ̀rọ̀ sísọ, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì? [be-YR ojú ìwé 111, àwọn àpótí]

2. Báwo la ṣe lè yí ìwọ̀n ìyárasọ̀rọ̀ wa padà nígbà tá a bá ń sọ àsọyé? [be-YR ojú ìwé 112 ìpínrọ̀ 3 sí 6, àpótí]

3. Kí la lè ṣe ká bàa lè fi ìtara sọ kókó ọ̀rọ̀ wa, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì? [be-YR ojú ìwé 115 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 116 ìpínrọ̀ 2, àpótí]

4. Nígbà tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa kọ́ wọn tọ̀yàyàtọ̀yàyà, kí ló sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa fi hàn? [be-YR ojú ìwé 118 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 119 ìpínrọ̀ 5]

5. Ṣàlàyé ọ̀nà tí ìfaraṣàpèjúwe àti ìrísí ojú gbà ṣe pàtàkì nígbà tá a bá ń bá àwọn èèyàn fèrò wérò. (Mát. 12:48, 49) [be-YR ojú ìwé 121, àwọn àpótí]

IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ

6. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa Jóòbù? [w94-YR 11/15 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 21]

7. Ọ̀nà wo ni inú rere onífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gbà “sàn ju ìyè” pàápàá lọ? (Sm. 63:3) [w86-YR 10/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 4 sí 5]

8. Nígbà tí Òwe 13:16 ń sọ nípa afọgbọ́nhùwà, ṣé alárèékérekè ló ń tọ́ka sí ni? Ṣàlàyé. [w04-YR 7/15 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 3 sí 4]

9. Ọ̀nà wo ni ẹ̀mí mímọ́ gbà ń ṣiṣẹ́ bí olùrànlọ́wọ́, kí ló sì yẹ kí mímọ èyí sún wa láti ṣe? (Jòh. 14:25, 26) [be-YR ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 2 sí 3]

10. Onírúurú ọ̀nà wo ni Jésù gbà dé, “dídé” wo sì ni Jésù sọ nípa rẹ̀ bó ṣe wà lákọọ́lẹ̀ nínú Mátíù 16:28? [w04-YR 3/1 ojú ìwé 16, àpótí]

BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀

11. Kí la lè rí kọ́ látinú èsì tí Jóòbù fún Jèhófà nínú Jóòbù 42:1-6?

12. “Nǹkan òfìfo” wo làwọn orílẹ̀-èdè ń sọ lábẹ́lẹ̀? (Sm. 2:1, 2)

13. Àwọn ìpìlẹ̀ wo ló wó lulẹ̀? (Sm. 11:3)

14. Báwo ni onírera ṣe ń ‘gba ẹ̀san ìwà rẹ̀ lọ́nà tó peléke’? (Sm. 31:23)

15. Báwo ni Sáàmù orí 40 ṣe lè tù wá nínú láti kojú àìpé ara ẹ̀ṣẹ̀ wa yìí àtàwọn àjálù mìíràn tí ètò àwọn nǹkan yìí ń fà? (Sm. 40:1, 2, 5, 12)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́