ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 6/06 ojú ìwé 2-3
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
km 6/06 ojú ìwé 2-3

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ó lò lóṣù June: Ẹ lo ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. Báwọn kan bá sì sọ pé àwọn kì í ṣe òbí, ẹ fún wọn ní ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. July àti August: Ẹ lè lo èyíkéyìí lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 yìí: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Ẹ Máa Ṣọ́nà! Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Ìwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọ́run Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I? àti “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.” September: Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni la ó lò. Ká sapá lákànṣe láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tá a bá bá onítọ̀hún pàdé. Gbogbo àwọn tá a fún ní ìwé ni ká ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn pẹ̀lú èrò àtibẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé.

◼ Níwọ̀n bí oṣù July ti ní òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún, ó máa jẹ́ oṣù tó túbọ̀ rọrùn láti ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.

◼ Bó o bá ní láti rìnrìn àjò lọ sí orílẹ̀-èdè kan tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, o ní láti jẹ́ kí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ìjọ rẹ gbọ́ kí wọ́n bàa lè kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè yẹn láti gba ìsọfúnni nípa orílẹ̀-èdè náà. Ẹ̀ka ọ́fíìsì yẹn ló máa pèsè ìsọfúnni nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ lórílẹ̀-èdè náà, bó ṣe mọ́gbọ́n dání tó láti rìnrìn àjò lọ síbẹ̀ àti bó o ṣe lè máa ṣe déédéé lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ lákòókò tó o bá fi wà ńbẹ̀.

◼ Kó bàa lè rọrùn fún ẹ̀ka ọ́fíìsì láti bójú tó lẹ́tà tó o bá kọ, o ní láti ṣe àwọn ohun tó tẹ̀lé e yìí: (1) Kọ orúkọ rẹ àti àdírẹ́sì rẹ sí igun lẹ́tà náà lápá ọ̀tún lókè. (2) Buwọ́ lù ú níbi tó bá parí sí, kó o sì kọ orúkọ rẹ sí abẹ́ ìbuwọ́lùwé náà torí a lè má lè lóye ìbuwọ́lùwé rẹ tàbí ká má lè kà á. A kì í ka lẹ́tà tí wọn kò buwọ́ lù tàbí èyí tẹ́ni tó kọ ọ́ kò kọ orúkọ rẹ̀ síbẹ̀ sí pàtàkì torí pé a ò mọ bó ṣe jóòótọ́ tó. Bó bá jẹ́ pé ṣe lo tẹ lẹ́tà náà, kì í ṣe pé kó o kàn tẹ orúkọ rẹ sí ìsàlẹ̀ rẹ̀ nìkan ni, torí ẹnikẹ́ni ló lè kọ lẹ́tà kó sì tẹ orúkọ rẹ sí ìparí rẹ̀. O gbọ́dọ̀ buwọ́ lù ú lókè orúkọ rẹ. Kó o tó fi lẹ́tà èyíkéyìí ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, jọ̀wọ́ wò ó láwòtúnwò láti rí i dájú pé o ti ṣe ohun méjì tá a mẹ́nu kàn yìí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́