Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 14
Orin 163
15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù August sílẹ̀. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 4 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ August 15 àti Jí! July-September. Nínú ọ̀kan lára àṣefihàn náà, fi hàn báwọn ara ṣe fún ẹni tí ò fẹ́ gbọ́rọ̀ wọn lésì, tó wá sọ pé “Èmi kò nífẹ̀ẹ́ sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.”—Wo ìwé Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Àwọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 9.
15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
15 min: “Rí I Pé O Ń Wá Ọ̀nà Láti Wàásù.”a Ní kí akéde kan tí ipò nǹkan ṣòro fún sọ ọ̀nà tó gbà wá àyè láti rí i pé òun ń wàásù.
Orin 84 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 21
Orin 62
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ àti Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
15 min: Bá A Ṣe Lè Jàǹfààní Látinú Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ àti Àsọyé fún Gbogbo Ènìyàn. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tó dá lórí ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, ojú ìwé 59 títí dé àkòrí tó wà lójú ìwé 64.
20 min: Bẹ̀rẹ̀ sí Í Ṣètò ní Báyìí Kó O Lè Wọṣẹ́ Aṣáájú-Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́! Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Fún àwọn ará níṣìírí pé kí wọ́n fi wíwọṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ṣe àfojúsùn wọn kódà kó jẹ́ fún oṣù kan péré nínú ọdún iṣẹ́ ìsìn tuntun. (1 Kọ́r. 9:26) Àwọn kan lè ṣe é lóṣù kan tó bọ́ sí àkókò ìgbòkègbodò àkànṣe tàbí oṣù tí wọ́n máa wà nínú ọlidé tàbí oṣù tó ní Sátidé àti Sunday márùn-ún. Bi àwùjọ pé: “Báwo lo ṣe borí àwọn ìṣòro tó o ti dojú kọ tó fi ṣeé ṣe fún ẹ láti wọṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́? Àwọn èrè wo lo ti rí nínú ṣíṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́? Bó bá ń wù ẹ́ láti wọṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ṣùgbọ́n tó o ṣì ń ṣiyè méjì, kí nìdí tó o fi gbọ́dọ̀ fi sínú àdúrà? (Ìṣe 4:29; 2 Kọ́r. 4:7; Ják. 1:5) Kí nìdí tó fi bójú mu pé kó o jíròrò ọ̀rọ̀ yìí pẹ̀lú ìdílé rẹ àtàwọn míì nínú ìjọ, pàápàá àwọn tí ipò yín jọra? (Òwe 15:22) Ìgbà wo lò ń gbèrò àtiwọṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́?”
Orin 216 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 28
Orin 17
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù August sílẹ̀. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 4 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ September 1 àti Jí! July-September nígbà tá a bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹni tó máa ń gba ìwé ìròyìn déédéé.
15 min: “Ìpolongo Kárí Ayé Tá A Ó Fi Kéde Àpéjọ Àgbègbè ‘Ìdáǹdè Kù sí Dẹ̀dẹ̀!’”b Rí i dájú pé gbogbo ìpínrọ̀ lẹ kà.
20 min: Ṣé Wàá Bẹ̀rẹ̀ sí Í Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lóṣù September? Àsọyé àti àṣefihàn. Lóṣù September, a máa sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà tá a bá kọ́kọ́ bá ẹnì kan sọ̀rọ̀. Láti lè ṣèyẹn, a máa rí i pé lákòókò tá a bá ń fún ẹni kan níwèé, a ó sapá láti jíròrò ìpínrọ̀ mélòó kan pẹ̀lú rẹ̀. Ṣe àṣefihàn méjì tó dá lórí kókó tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, jẹ́ kí àwùjọ rí bí wọ́n ṣe lè ṣe àdéhùn pàtó tó máa jẹ́ kí wọ́n lè ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹni náà láti tẹ̀ síwájú nínú ìjíròrò náà.
Orin 37 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 4
Orin 90
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
20 min: O Lè Fún Ẹnì Kan Níṣìírí. (Róòmù 1:11, 12) Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Sọ iye aṣáájú-ọ̀nà déédéé tó wà nínú ìjọ. Mẹ́nu ba àwọn ọ̀nà tá a lè gbà fún wọn níṣìírí, bíi gbígbóríyìn fún wọn, sísọ ohun tó dáa nípa iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, bíbá wọn ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá, pípè wọ́n wá jẹun, sísan owó ọkọ̀ tí wọ́n bá rìnrìn àjò. Ní káwọn aṣáájú-ọ̀nà sọ àwọn ọ̀nà táwọn ará ti gbà fún wọn níṣìírí. Bí ò bá sí àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé nínú ìjọ yín, kúkú jíròrò bá a ṣe lè fún àwọn aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ níṣìírí.
15 min: “Fi Hàn Pé Ọ̀rọ̀ Àwọn Èèyàn Jẹ Ọ́ Lógún—Nípa Wíwàásù fún Gbogbo Èèyàn Láìdá Ẹnì Kan Sí.”c Nígbà tó o bá ń jíròrò Róòmù 1:14 tó wà ní ìpínrọ̀ 2, fi àlàyé ṣókí kún un látinú ìwé Insight (Gẹ̀ẹ́sì), Ìdìpọ̀ 1, ojú ìwé 255, ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ lábẹ́ àkòrí náà “Barbarian” [Aláìgbédè]. Lẹ́yìn tó o bá ti jíròrò ìpínrọ̀ 3, jíròrò àwọn ìgbésẹ̀ mẹ́tà tó wà ní ojú ìwé 2 nínú ìwé pẹlẹbẹ Good News for People of All Nations, kó o sì ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo ìwé pẹlẹbẹ náà fáwọn èèyàn tó ń sọ èdè míì ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa.
Orin 225 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.