Àwọn Ìbéèrè Tá a Máa Lò Fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
Bá a ṣe máa lo ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà fún ìkẹ́kọ̀ọ́
Kó o bàa lè kẹ́kọ̀ọ́ ìwé yìí lọ́nà tó gbámúṣé, á dáa kó o kọ nọ́ńbà sáwọn ìpínrọ̀ tó wà ní orí kọ̀ọ̀kan, títí kan àwọn ìpínrọ̀ tó wà nínú ọ̀rọ̀ ìṣáájú. Gbogbo ìpínrọ̀ tó bá wà nínú ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan ni kó o sì máa kà pa pọ̀. Bẹ́ ẹ bá ṣe ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ, ẹ lè jíròrò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà ní ìparí orí kọ̀ọ̀kan nígbà tó bá yẹ.
Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ka ìwé yìí ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ, orí méjì ni kẹ́ ẹ máa kà lọ́sẹ̀ kọ̀ọ̀kan, kẹ́ ẹ fi ọ̀rọ̀ ìṣáájú ṣe orí kìíní. Ọ̀sẹ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n lẹ máa fi kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìwé yìí, kẹ́ ẹ fi ọ̀sẹ̀ tó bá kẹ́yìn jíròrò Orí 48 tó gbẹ̀yìn pẹ̀lú àtúnyẹ̀wò ráńpẹ́ nínú ìwé yìí.
Orí 32 Ìpínrọ̀ 1 sí 9
1. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń rí i dájú pé òún dáàbò bo àwọn ọmọ ẹyẹ?
2. Ìgbà wo ni Jésù nílò ààbò, ààbò kúrò lọ́wọ́ ta sì ni?
3. Báwo ni Jèhófà ṣe dáàbò bo Ọmọ rẹ̀ kí wọ́n má bàa pá?
Ìpínrọ̀ 10 sí 13
4. Àwọn wo lónìí ló dà bí i Jésù nígbà tó wà lọ́mọdé, kí sì nìdí tí wọ́n fi nílò ààbò?
5. Báwo ni Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ṣe máa ń ṣàkóbá fáwọn ọmọ kéékèèké?
6. Àwọn wo ló yẹ kí wọ́n máa bá ara wọn lò pọ̀, irú ìbálòpọ̀ wo sì ni Ọlọ́run kórìíra?
Ìpínrọ̀ 14 sí 17
7. Àwọn wo ló lè gbìyànjú láti bá àwọn ọmọdé ṣèṣekúṣe, ọgbọ́n wo ni wọ́n sì máa ń dá káwọn ọmọdé má bàa tú àṣírí wọn?
8. Báwo làwọn ọmọdé ṣe lè dáàbò bo ara wọn kúrò lọ́wọ́ àwọn tó ń ṣe ohun burúkú wọ̀nyẹn?
9. Kí làwọn òbí lè ṣe láti dáàbò bo àwọn ọmọ wọn?
Orí 33 Ìpínrọ̀ 1 sí 8
1. Kí lọ̀pọ̀ èèyàn ń rò nípa Jésù lóde òní, àmọ́ ní báyìí irú ẹni wo ni Jésù jẹ́?
2. Lọ́jọ́ kan tí Jésù wà pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú omi, báwo ló ṣe fi hàn pé òún ní agbára ńlá?
3. Kí nìdí tí kò fi yẹ káwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù bẹ̀rù?
Ìpínrọ̀ 9 sí 14
4. Kí ló ṣẹlẹ̀ ní àkókò míì tí ẹ̀fúùfù òkun tún ń fẹ́?
5. Kí nìdí tí Jésù fi ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyẹn lákòókò náà?
Ìpínrọ̀ 15 àti 16
6. Báwo ni Jésù ṣe ń lo agbára rẹ̀ lónìí?
7. Àwọn iṣẹ́ ìyanu wo la lè máa fojú sọ́nà fún lọ́jọ́ iwájú?
Orí 34 Ìpínrọ̀ 1 sí 4
1. Báwo la ṣe lè mọ ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí ẹnì kan bá kú?
2. Kí lohun tí Jésù sọ nígbà tí Lásárù kú fi hàn nípa ikú?
Ìpínrọ̀ 5 sí 10
3. Kí ni Jésù ṣe níbi ibojì Lásárù?
4. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù kígbe lóhùn rara pé: “Lásárù, jáde wá!”?
Ìpínrọ̀ 11 sí 16
5. Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí ẹnì kan bá kú?
6. Báwo la ṣe mọ̀ pé Lásárù kò lọ sọ́run nígbà tó kú?
7. Báwo la ṣe mọ̀ pé nígbà tí ẹnì kan bá kú, ọkàn kan ti kú nìyẹn?
Ìpínrọ̀ 17 sí 19
8. Kí làwọn èèyàn gbà gbọ́ ládùúgbò yín nípa àwọn òkú?
9. Báwo ni ìtàn Lásárù ò ṣe ní jẹ́ ká máa bẹ̀rù àwọn òkú?
Orí 35 Ìpínrọ̀ 1 sí 4
1. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ láti jí àwọn òkú dìde àti pé Jésù pàápàá fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀?
2. Báwo ni wọ́n ṣe jí àwọn ọmọ kékeré méjì kan dìde ṣáájú kí wọ́n tó bí Jésù?
3. Kí nìdí tó fi lè dá wa lójú pé Jèhófà máa rántí wa tá a bá kú?
Ìpínrọ̀ 5 sí 11
4. Kí ló ṣe ọmọbìnrin Jáírù, kí ni Jésù sì ṣe fún un?
5. Ẹ̀kọ́ wo ni ìtàn Bíbélì yìí kọ́ wa?
Ìpínrọ̀ 12 sí 18
6. Báwo ni jíjí tí Jésù jí ọmọkùnrin opó kan dìde ṣe fi hàn pé ó ń fẹ́ láti jí àwọn òkú dìde?
7. Báwo lo ṣe rò pó máa rí lára ìyá ọmọkùnrin tí Jésù jí dìde yẹn, nígbà wo sì làwọn mìíràn máa nírú ìmọ̀lára kan náà?
Orí 36 Ìpínrọ̀ 1 sí 6
1. Kí làwọn àjíǹde tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn fi hàn?
2. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi máa jí àwọn aláìṣòdodo dìde, ibo ni wọ́n sì máa gbé?
3. Ìgbà wo ni àjíǹde máa wáyé lórí ilẹ̀ ayé, kí ló sì máa ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn?
Ìpínrọ̀ 7 sí 11
4. Kí la rí kọ́ látinú ìlérí tí Jésù ṣe fún ọ̀daràn yẹn pé ó máa wà pẹ̀lú òun ní Párádísè?
5. Lọ́nà wo ni Jésù máa gbà wà pẹ̀lú ọ̀daràn yẹn ní Párádísè?
6. Kí nìdí tí Jésù fi máa gba ọkùnrin tó ti jẹ́ ọ̀daràn tẹ́lẹ̀ rí yìí láyè láti gbé nínú Párádísè?
Ìpínrọ̀ 12 sí 17
7. Báwo la ṣe mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo àwọn tó bá jíǹde ló máa gbé lórí ilẹ̀ ayé?
8. Àwọn mélòó ni yóò nípìn-ín nínú “àjíǹde èkíní,” kí ni wọ́n sì máa ṣe?
9. Kí nìdí tó fi máa jẹ́ ohun alárinrin láti máa gbé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé?
Orí 37 Ìpínrọ̀ 1 sí 7
1. Ẹ̀bùn pàtàkì wo ni Ọlọ́run fún wa?
2. Kí nìdí tí gbogbo wa fi nílò bàbá tuntun kan?
3. Báwo ni Jésù ṣe lè di bàbá àti Olùgbàlà fún wa?
4. Kí ni ìràpadà, kí sì nìdí tá a fi nílò rẹ̀?
Ìpínrọ̀ 8 sí 15
5. Ìrántí kí ni Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe lálẹ́ ọjọ́ tó ku ọ̀la kó kú?
6. Ìrántí kí ni Jésù wá fi lélẹ̀ láti fi rọ́pò Ìrékọjá?
7. Àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ wo ni Jésù lò fún ìrántí tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀, kí ni wọ́n sì dúró fún?
8. Kí ni ohun tí Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ yìí rán wa létí rẹ̀?
Ìpínrọ̀ 16 sí 18
9. Kí ló yẹ ká máa ronú nípa rẹ̀ nígbà tá a bá lọ síbi Ìrántí Ikú Kristi?
10. Àwọn wo ló lè jẹ búrẹ́dì kí wọ́n sì mu nínú wáìnì náà, kí nìdí?
11. Kí nìdí táwọn tí kò ní jẹ nínú búrẹ́dì tàbí mu wáìnì náà fi gbọ́dọ̀ wà níbẹ̀?
Orí 38 Ìpínrọ̀ 1 sí 5
1. Ọwọ́ kí ni Jésù ti gbà wá?
2. Àwọn wo ni Jésù kú fún?
3. Báwo ni Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ aráyé tó?
Ìpínrọ̀ 6 sí 12
4. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Jésù ní alẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ikú rẹ̀?
5. Kí làwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ tó tẹ̀ lé e?
6. Kí làwọn ohun tó mú kí Jésù yàtọ̀ sí Ádámù?
Ìpínrọ̀ 13 sí 16
7. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé òun mọrírì ìfẹ́ tí Kristi ní fún òun?
8. Kí nìdí pàtàkì tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ Jésù?
9. Báwo la ṣe lè fi hàn pé à ń lo ìwàláàyè wa fún ṣíṣe ohun tí Kristi fẹ́?
Orí 39 Ìpínrọ̀ 1 sí 4
1. Báwo lo ṣe rò pó máa rí lára Jèhófà nígbà tí wọ́n pa Jésù?
2. Kí ló dá Jésù lójú?
3. Láti ibo ni Ọlọ́run ti jí Jésù dìde, ọjọ́ mélòó ló sì lò níbẹ̀?
Ìpínrọ̀ 5 sí 13
4. Sọ àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ Friday tí Jésù kú.
5. Irú ara wo ni Ọlọ́run fún Jésù nígbà tó jí i dìde, báwo sì làwọn èèyàn ṣe rí i lẹ́yìn ìgbà yẹn?
6. Kí làwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ Sunday tí Jésù jíǹde?
Ìpínrọ̀ 14 sí 17
7. Ọjọ́ mélòó ni Jésù fi fara han àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lẹ́yìn tó jíǹde, kí sì làwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìgbà yẹn?
8. Báwo ni ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ṣe máa ń ṣe ọdún àjíǹde, àmọ́ báwo làwa ṣe lè ṣe bíi tàwọn ọmọlẹ́yìn Jésù àtijọ́?
Orí 40 Ìpínrọ̀ 1 sí 3
1. Kí ni Ọlọ́run ò béèrè pé ká ṣe, àmọ́ kí la lè ṣe?
2. Kí nìdí tí Ọlọ́run ò fi dá wa bí ẹ̀rọ ká lè máa ṣe àwọn ohun tó fẹ́?
Ìpínrọ̀ 4 sí 7
3. Báwo lo ṣe rò pó máa rí lára Ọlọ́run tá a bá ṣe ìfẹ́ rẹ̀?
4. Kí nìdí tí yíyàn tá a bá ṣe nípa ẹni tá a fẹ́ sìn fi ṣe pàtàkì sí Jèhófà àti sí Sátánì?
Ìpínrọ̀ 8 sí 15
5. Kí ni Sátánì ṣe fún Jóòbù?
6. Báwo lo ṣe rò pé jíjẹ́ tí Jóòbù jẹ́ olódodo ṣe máa rí lára Jèhófà?
7. Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ fún wa, báwo la sì ṣe lè fara wé e?
Orí 41 Ìpínrọ̀ 1 sí 7
1. Kí ni Jésù ṣe tó mú káwọn òbí rẹ̀ dààmú nígbà kan?
2. Kí ni Jésù ṣe nígbà tó wà lọ́mọdé tó múnú àwọn òbí rẹ̀ àti Ọlọ́run dùn?
Ìpínrọ̀ 8 sí 12
3. Kí lọmọ kan lè máa ṣe lónìí tó máa múnú Ọlọ́run dùn?
4. Báwo la ṣe lè mọ àwọn tó jẹ́ èèyàn Ọlọ́run?
Ìpínrọ̀ 13 sí 18
5. Báwo ni àpẹẹrẹ Tímótì ṣe lè ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́?
6. Kí la lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ ọ̀dọ́mọbìnrin Ísírẹ́lì kan?
7. Ohun tó dáa wo làwọn ọmọ kéékèèké lè pinnu láti ṣe?
Orí 42 Ìpínrọ̀ 1 sí 6
1. Báwo la ṣe mọ̀ pé kò sóhun tó burú nínú ṣíṣe eré ìtura?
2. Iṣẹ́ wo ni Bíbélì sọ pé Jésù kọ́, kí sì nìdí tó o fi gbà pé Jésù mọ iṣẹ́ yẹn dunjú?
3. Kí nìdí tí iṣẹ́ ṣíṣe fi dùn mọ́ Jésù, kí sì nìdí tó fi dára káwa náà máa ṣiṣẹ́?
Ìpínrọ̀ 7 sí 13
4. Kí ló ń múnú Jésù dùn?
5. Iṣẹ́ àkànṣe wo ni Jésù ṣe nígbà tó wà láyé, báwo sì ni iṣẹ́ ọ̀hún ṣe rí lára rẹ̀?
6. Àwọn iṣẹ́ wo làwọn ọmọdé lè ṣe, àǹfààní wo sì làwọn iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ lè ṣe fún ìdílé?
Ìpínrọ̀ 14 sí 16
7. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn ọmọdé máa ṣe iṣẹ́ ilé ìwé wọn?
8. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa sá fún iṣẹ́?
9. Ìbéèrè pàtàkì wo ló yẹ ká máa bi ara wa nípa iṣẹ́ ṣíṣe?
Orí 43 Ìpínrọ̀ 1 sí 7
1. Kí la mọ̀ nípa àwọn ọmọ ìyá Jésù lọ́kùnrin àti lóbìnrin?
2. Àwọn wo ni Jésù pè ní ìyá àti arákùnrin òun, kí ló sì ní lọ́kàn nígbà tó sọ bẹ́ẹ̀?
3. Irú ìwà wo ló ti ṣeé ṣe káwọn mọ̀lẹ́bí Jésù ti kọ́kọ́ hù sí i?
Ìpínrọ̀ 8 sí 14
4. Àpẹẹrẹ àwọn ọmọ ìyá kan náà wo la rí nínú Bíbélì tí wọn ò fẹ́ràn ara wọn?
5. Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la lè rí kọ́ látinú ìtàn Kéènì àti Ébẹ́lì?
Ìpínrọ̀ 15 sí 18
6. Kí ni ìfẹ́, báwo ló sì ti ṣe pàtàkì tó pé ká fi hàn?
7. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa?
Orí 44 Ìpínrọ̀ 1 sí 5
1. Báwo la ṣe lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run bí i ti Ábúráhámù?
2. Àwọn wo lọ̀rẹ́ Jésù?
3. Àwọn wo ló wà lára àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ Jésù?
Ìpínrọ̀ 6 sí 10
4. Kí nìdí tí Jésù fi máa ń lọ sílé onírúurú èèyàn?
5. Ta ni Sákéù, báwo ló sì ṣe di ọ̀rẹ́ Jésù?
Ìpínrọ̀ 11 sí 15
6. Kí nìdí tó fi yẹ ká lọ sílé àwọn tí kì í ṣe ọ̀rẹ́ wa?
7. Àwọn wo la lè fi ṣọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́?
8. Báwo la ṣe lè mọ̀ bóyá ẹnì kan lè di ọ̀rẹ́ tó dára?
9. Báwo ni àwọn tá à ń bá kẹ́gbẹ́ ṣe lè nípa lórí ìgbésí ayé wa?
Orí 45 Ìpínrọ̀ 1 sí 8
1. Kí ni Ìjọba Ọlọ́run, kí la sì mọ̀ nípa alákòóso rẹ̀?
2. Kí nìdí tí Jésù fi sọ pé Ìjọba náà ti sún mọ́lé nígbà tó wà láyé?
3. Iṣẹ́ pàtàkì wo ni Jésù ṣe nígbà tó wà láyé, àwọn wo ló sì ràn án lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà?
Ìpínrọ̀ 9 sí 14
4. Àwọn wo ló fẹ́ kí Jésù jẹ Ọba wọn, àwọn wo ni kò sì fẹ́?
5. Àwọn wo ló fẹ́ pa Jésù, báwo ni wọ́n sì ṣe yí àwọn èèyàn lọ́kàn padà?
6. Báwo làwọn èèyàn ṣe nífẹ̀ẹ́ Jésù sí lónìí?
Ìpínrọ̀ 15 sí 20
7. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a fẹ́ràn Ọlọ́run?
8. Kí ni ìrìbọmi tí Jésù ṣe fi hàn pé ó fẹ́ láti ṣe, báwo sì ni Ọlọ́run ṣe fi hàn pé òún tẹ́wọ́ gbà á?
9. Kí nìdí tó fi yẹ káwa náà ṣèrìbọmi, iṣẹ́ pàtàkì wo ló sì yẹ ká máa ṣe lọ lẹ́yìn ìgbà náà?
Orí 46 Ìpínrọ̀ 1 sí 11
1. Kí ni ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ inú Bíbélì náà pé “ayé ń kọjá lọ”?
2. Kí làwọn èèyàn ń ṣe ṣáájú Ìkún Omi, kí sì nìdí tí Jésù fi fẹ́ ká mọ̀ nípa rẹ̀?
3. Àwọn ìtọ́ni wo ni Ọlọ́run fún Nóà, kí ló sì ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ìkún Omi dé?
Ìpínrọ̀ 12 sí 19
4. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ìwà àwọn èèyàn tó wà ṣáájú Ìkún Omi?
5. Kí ni Ọlọ́run máa fi pa àwọn èèyàn búburú run, kí sì nìdí?
6. Kí ni Amágẹ́dọ́nì, ta ló sì máa jẹ́ aṣáájú nínú rẹ̀?
Orí 47 Ìpínrọ̀ 1 sí 11
1. Báwo làwọn èèyàn ṣe máa mọ̀ pé Jésù ti padà dé àti pé ó ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso lọ́run?
2. Ẹ̀kọ́ wo ni Jésù ń kọ́ àwọn èèyàn nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa igi ọ̀pọ̀tọ́?
3. Àwọn wo lára àmì tí Jésù sọ ló ti ń ṣẹ lónìí?
Ìpínrọ̀ 12 sí 16
4. Kí ni àmì tí Jésù sọ túmọ̀ sí?
5. Nígbà tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa sísá àsálà nígbà òtútù, ẹ̀kọ́ wo ló fìyẹn kọ́ wa?
Orí 48 Ìpínrọ̀ 1 sí 4 àti ojú ìwé 251 sí 254
1. Kí ni “ọ̀run tuntun” àti “ilẹ̀ ayé tuntun” túmọ̀ sí?
2. Lo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ àtàwọn àwòrán tó wà nínú ìwé yìí láti fi ṣàlàyé bí nǹkan ṣe máa rí nínú ayé tuntun Ọlọ́run.
Ojú ìwé 250 ìpínrọ̀ 5 àti ojú ìwé 255 sí 256
3. Kí nìdí tá a fi ní láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ká tó lè wà láàyè títí láé?
4. Kí la tún gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè wà láàyè títí láé nínú ayé tuntun Ọlọ́run?
5. Báwo ni ìwé yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ká bàa lè wà láàyè títí láé?