ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/07 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 10
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 17
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 24
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 1
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
km 9/07 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Àkíyèsí: Bó ti ṣe máa ń rí, ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tá a máa ṣe lọ́sẹ̀ kọ̀ọ̀kan jálẹ̀ àkókò àpéjọ àgbègbè máa wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Kí ìjọ kọ̀ọ̀kan ṣe àyípadà tó bá yẹ kí wọ́n bàa lè wà ní Àpéjọ Àgbègbè “Máa Tọ Kristi Lẹ́yìn.” Níbi tó bá ti yẹ bẹ́ẹ̀, kẹ́ ẹ lo ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tẹ́ ẹ máa ṣe kẹ́yìn kẹ́ ẹ tó lọ sí àpéjọ náà láti tún jíròrò àwọn ìmọ̀ràn pàtàkì tó kan ìjọ yín nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí. Lẹ́yìn oṣù kan tàbí méjì tẹ́ ẹ bá ti ṣe àpéjọ àgbègbè yín, kẹ́ ẹ ya ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí ogún ìṣẹ́jú sọ́tọ̀ ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn (ẹ sì lè lo apá tó jẹ́ ti àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ) láti fi ṣàtúnyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì inú àpéjọ náà táwọn ará ti rí i pé ó wúlò fáwọn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó ṣe iṣẹ́ yìí. Ní kí àwùjọ sọ bí wọ́n ṣe fi ohun tí wọ́n kọ́ ní àpéjọ náà sílò tàbí ọ̀nà tí wọ́n ń rò lọ́kàn láti gbà fi í sílò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 10

Orin 225

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù September sílẹ̀. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ míì tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ September 15 àti Jí! July–September. (Lo àbá kẹta lójú ìwé 8 fún Jí! July–September.) Ìwé ìròyìn méjèèjì ni kó o fún onílé lẹ́ẹ̀kan náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé orí ọ̀kan nínú ẹ̀ ni àlàyé ẹ máa dá lé.

15 min: Àpótí Ìbéèrè. Alàgbà ni kó ṣe iṣẹ́ yìí lọ́nà ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Bí àkókò bá ṣe wà sí, ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a fà yọ, kó o sì jíròrò wọn.

20 min: “Bá A Ṣe Máa Pe Àwọn Èèyàn Síbi Àpéjọ Àgbègbè “Máa Tọ Kristi Lẹ́yìn!” Tá A Máa Ṣe Jákèjádò Ayé!”a Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 3, ní kí àwùjọ sọ ìrírí tó ta yọ tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n ń pín ìwé tá a fi pe àwọn èèyàn sí àpéjọ àgbègbè tọdún tó kọjá tàbí kó o fi àlàyé kún un látinú ìwé ọdọọdún 2007 Yearbook, láti ojú ìwé 7 sí ìsọ̀rí tó wà lójú ìwé 10.

Orin 43 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 17

Orin 60

5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

20 min: “Máa Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Tí Jésù Fi Lélẹ̀.”b Ní kí àwùjọ sọ àǹfààní tí wọ́n ti rí látinú àpẹẹrẹ rere àwọn ẹlòmíì.

20 min: Ẹgbẹ́ Ará Tó Wà Níṣọ̀kan. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, orí 16.

Orin 74 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 24

Orin 162

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́.

12 min: “Ojú Tó Yẹ Ká Máa Fi Wo Àwọn Ìtẹ̀jáde Wa àti Bó Ṣe Yẹ Ká Máa Lò Wọ́n.”c

23 min: “Máa Tọ Kristi Lẹ́yìn Nípa Ṣíṣe Ohun Tó Buyì Kún Jèhófà.”d Akọ̀wé ìjọ ni kó ṣe iṣẹ́ yìí. Sọ déètì àti ibi tí ìjọ yín ti máa ṣe àpéjọ àgbègbè tọdún yìí. Jíròrò àpótí náà, “Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Nípa Àpéjọ Àgbègbè.”

Orin 44 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 1

Orin 88

8 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ àtàwọn ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù September sílẹ̀.

12 min: Lẹ́tà Láti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tó dá lórí lẹ́tà tó wà lójú ewé àkọ́kọ́ nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí.

10 min: Ibo La Báṣẹ́ Dé Lọ́dún Tó Kọjá? Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó bójú tó iṣẹ́ yìí, kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ dá lórí ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá, kó sọ̀rọ̀ nípa àwọn àṣeyọrí tá a ṣe nínú iṣẹ́ ìwàásù. Yin àwùjọ fún ohun ribiribi tí wọ́n ṣe. Mẹ́nu ba ohun kan tàbí méjì tó yẹ kí wọ́n ṣiṣẹ́ lé lórí lọ́dún iṣẹ́ ìsìn tó ń bọ̀. Sọ̀rọ̀ nípa ìgbòkègbodò àwọn aṣáájú-ọ̀nà. Yìn wọ́n nítorí bí wọ́n ṣe ń fìtara ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Sọ àṣeyọrí tá a ti ṣe látàrí bá a ṣe ń ran àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́wọ́.

15 min: “Bá A Ṣe Lè Túbọ̀ Tẹra Mọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa.”e Ní káwọn ará sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe lè túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, kó o sì jẹ́ kí wọ́n sọ onírúurú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe é. O lè ti ní kí ẹnì kan tàbí méjì múra sílẹ̀ láti sọ̀rọ̀.

Orin 102 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

e Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́