ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/07 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 12
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 19
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 26
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 3
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
km 11/07 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 12

Orin 59

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ti ìlàjì oṣù November sílẹ̀. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 4 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ míì tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ November 15 àti Jí! October-December. (Lo àbá kẹta lójú ìwé 4 fún Jí! October–December.) Ìwé ìròyìn méjèèjì ni kó o fún onílé lẹ́ẹ̀kan náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé orí ọ̀kan nínú ẹ̀ ni àlàyé ẹ máa dá lé.

15 min: “Tèmi Ni Fàdákà, Tèmi sì Ni Wúrà.” Àsọyé tí alàgbà kan yóò sọ, tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ November 1, 2007 ojú ìwé 17 sí 21.

20 min: “Máa Rìn bí Ọlọ́gbọ́n.”a Bí àyè bá ṣe wà sí, ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí.

Orin 192

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 19

Orin 109

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Mẹ́nu ba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a máa lò ní oṣù December, kó o sì ṣe àṣefihàn kan nípa bá a ṣe máa gbọ́rọ̀ kalẹ̀.

15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

20 min: “Má Ṣaláì Ṣe É!”b Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 5, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn tó ti ran àwọn kan lọ́wọ́ láti wá sínú òtítọ́. Kí wọ́n ṣàlàyé bí dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń tẹ̀ síwájú ṣe ń sèso tó sì ń gbádùn mọ́ni. O lè ti sọ fẹ́nì kan tàbí ẹni méjì kó tó dìgbà tó o máa ṣiṣẹ́ yìí pé kí wọ́n múra àwọn àlàyé kan sílẹ̀.

Orin 96

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 26

Orin 172

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù November sílẹ̀. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 4 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ míì tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ December 1 àti Jí! October–December. (Lo àbá kẹrin lójú ìwé 4 fún Jí! October–December.)

15 min: Ǹjẹ́ O Lè Mú Kí Ìfẹ́ Rẹ Gbòòrò Sí I? Àsọyé tí alàgbà kan yóò sọ, tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ January 1, 2007, ojú ìwé 9 sí 11.

20 min: Ẹ̀yin Èwe—Báwo Lẹ Ṣe Lè Máa Yin Jèhófà? Ìjíròrò látinú Ilé Ìṣọ́ June 15, 2005, ojú ìwé 26 sí 28, ìpínrọ̀ 15 sí 19. Lo àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà fún ìjíròrò yìí. Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 18, ní kí àwọn ọ̀dọ́ tó wà láàárín àwùjọ sọ bí wọ́n ṣe wàásù fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn tàbí àwọn olùkọ́ wọn níléèwé.

Orin 5

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 3

Orin 77

15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Sọ̀rọ̀ lórí Àpótí Ìbéèrè.

15 min: Ilé Ẹ̀kọ́ Kan Táwọn Tó Jáde Níbẹ̀ Ń Ṣe Àwọn Èèyàn Láǹfààní Jákèjádò Ayé. Àsọyé tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ November 15, 2006, ojú ìwé 10 sí 13. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó ti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ látinú ìjọ yín. Kí wọ́n ṣàlàyé bí ilé ẹ̀kọ́ náà ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere, alábòójútó àti olùkọ́. Gba àwọn arákùnrin tó tóótun nímọ̀ràn láti fi Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ṣe àfojúsùn wọn.

15 min: “À Ń Wàásù Ìhìn Rere Ìjọba Ọlọ́run Fáwọn Ẹlòmíì.”c Bí àyè bá ṣe wà sí, ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí.

Orin 173

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́