Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè àtúnyẹ̀wò tó wà nísàlẹ̀ yìí la óò gbé yẹ̀ wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní August 25, 2008. Àtúnyẹ̀wò yìí dá lórí àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe lọ́sẹ̀ July 7 sí August 25, 2008, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò sì darí rẹ̀ fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú.
ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ
1. Báwo la ṣe lè lo ìfòyebánilò nígbà tá a bá ń wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn? (Fílí. 4:5) [be-YR ojú ìwé 251 ìpínrọ̀ 3]
2. Kí la lè rí kọ́ látinú bí Pọ́ọ̀lù ṣe bá àwọn Gíríìkì sọ̀rọ̀ ní Áréópágù nígbà tá a bá ń wàásù fáwọn tí ò ka Bíbélì sí Ìwé Mímọ́? (Ìṣe 17:22, 23) [be-YR ojú ìwé 252 ìpínrọ̀ 1 àti 2]
3. Bá a bá tiẹ̀ mọ̀ pé ohun tẹ́ni tá à ń bá sọ̀rọ̀ ń sọ ò tọ̀nà, báwo la ṣe lè fòye bá a lò? [be-YR ojú ìwé 253 ìpínrọ̀ 1 àti 2]
4. Bá a ṣe ń gbìyànjú láti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa yí àwọn èèyàn lọ́kàn padà, kí la ò gbọ́dọ̀ gbàgbé? [be-YR ojú ìwé 255 ìpínrọ̀ 3 àti àpótí]
5. Báwo la ṣe lè lo ìfòyemọ̀ nígbà tá a bá ń gbìyànjú láti dé ọkàn-àyà àwọn olùgbọ́ wa? (Òwe 20:5) [be-YR ojú ìwé 258 ìpínrọ̀ 1 sí 5]
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ
6. Kí làwọn arábìnrin gbọ́dọ̀ máa fi sọ́kàn nígbà tí wọ́n bá fún wọn níṣẹ́ tó ń béèrè pé kí wọ́n yan ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀? [be-YR ojú ìwé 44 ìpínrọ̀ 5 àti 6]
7. Kí làwọn arákùnrin gbọ́dọ̀ máa ṣe nígbà tí wọ́n bá ń bójú tó kókó pàtàkì látinú Bíbélì? (Neh. 8:8) [be-YR ojú ìwé 47 ìpínrọ̀ 2 àti 3]
8. Bí iṣẹ́ kan nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn bá ní àṣefihàn tàbí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò nínú, báwo ló ṣe yẹ ká bójú tó o? [be-YR ojú ìwé 49 ìpínrọ̀ 5]
9. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà fi kọ̀ jálẹ̀ nígbà táwọn ará Lísírà fẹ́ fi òdòdó ẹ̀yẹ rúbọ sí wọn? (Ìṣe 14:8-18) [w90-YR 5/15 ojú ìwé 25, àpótí kẹta]
10. Kí ni alásọyé lè ṣe láti rí i dájú pé Bíbélì lòún gbé ọ̀rọ̀ òun kà? (Ìṣe 17:2, 3) [be-YR ojú ìwé 52 ìpínrọ̀ 6 sí ojú ìwé 53 ìpínrọ̀ 2]
BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀
11. Kí nìdí tí onítúbú ará Fílípì náà fi fẹ́ “pa ara rẹ̀”? (Ìṣe 16:25-27) [w90-YR 5/15 ojú ìwé 25, àpótí]
12. Kí ni Àrísítákọ́sì àti Gáyọ́sì ṣe nígbà tí wọ́n ṣe inúnibíni sí wọn? (Ìṣe 19:29; 20:4, 5) [w08-YR 2/15 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 16 àti 17]
13. Kí ni ìtúmọ̀ gbólóhùn náà pé Sọ́ọ̀lù ń bá a nìṣó ní “títàpá sí ọ̀pá kẹ́sẹ́”? (Ìṣe 26:14) [w03-YR 10/1 ojú ìwé 32]
14. Báwo ni ẹ̀ṣẹ̀ ṣe lè gba “ìsúnniṣe nípasẹ̀ àṣẹ” tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì? (Róòmù 7:8, 11) [w08-YR 6/15 “Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè—Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Róòmù”]
15. Báwo la ṣe ń kó “òkìtì ẹyín iná” lé ọ̀tá lórí? (Róòmù 12:20) [w08-YR 6/15 “Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè—Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Róòmù”]