Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a ó lò lóṣù August: Ẹ lè lo èyíkéyìí lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 yìí: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Ẹ Máa Ṣọ́nà!, Ẹmi Awọn Oku-Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Ìwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun-Ṣé O Ti Rí I? àti “Sáwo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.” September: Ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? la máa lò. Ẹ sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́jọ́ tẹ́ ẹ bá kọ́kọ́ bá onílé sọ̀rọ̀. Tí onílé bá sì ti ní ìwé yìí, ẹ fi bó ṣe lè jàǹfààní látinú rẹ̀ hàn án nípa jíjẹ́ kó mọ bá a ṣe ń fìwé náà báwọn èèyàn ṣèkẹ́kọ̀ọ́. October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Bí ẹni náà bá nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ wa, ẹ jíròrò ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì? pẹ̀lú rẹ̀, kẹ́ ẹ sì ní in lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ sí í bá a ṣèkẹ́kọ̀ọ́. November: Ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
◼ Káwọn alàgbà má gbàgbé láti ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìtọ́ni tó wà nínú Ilé-Ìṣọ́nà April 15, 1991, ojú ìwé 21 sí 23, tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn tá a yọ lẹ́gbẹ́ tàbí tí wọ́n yọ ara wọn lẹ́gbẹ́, tí wọ́n lè fẹ́ ká gba àwọn padà.