ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/08 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 11
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 18
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 25
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 1
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
km 8/08 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 11

Orin 63

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ní káwọn ará sọ àwọn àpilẹ̀kọ, tó wà nínú àwọn ìwé ìròyìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé, tó ṣeé ṣe kó fa àwọn èèyàn lọ́kàn mọ́ra ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Ní kí wọ́n mẹ́nu ba àwọn kókó kan látinú àwọn àpilẹ̀kọ tí wọ́n ní lọ́kàn láti lò lóde ẹ̀rí. Ìbéèrè wo ni wọ́n lè fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò? Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ni wọ́n máa fẹ́ láti kà látinú àpilẹ̀kọ náà? Ṣètò àṣefihàn bá a ṣe lè fi ìwé ìròyìn kọ̀ọ̀kan lọni.

15 min: Ṣe Ìfẹ́ Ọlọ́run Láìsí Ìpínyà Ọkàn. Àsọyé tá a gbé ka ìwé “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn,” ojú ìwé 93 àti 94, ìpínrọ̀ 12 àti 13.

20 min: “Ṣé Gbogbo Àpilẹ̀kọ Tó Wà Nínú Rẹ̀ Lò Ń Lò?”a Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tó ti lo ọ̀kan lára àwọn àpilẹ̀kọ tuntun tó wà nínú ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tá à ń fi sóde. O lè ní kó ṣàṣefihàn bó ṣe ṣe é. Pẹ̀lú ohun tó wà ní ìpínrọ̀ 2, tún ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nípa lílo “Ohun Tá A Kọ́ Lọ́dọ̀ Jésù” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ August 1.

Orin 26

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 18

Orin 135

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Rán àwọn ará létí pé kí wọ́n fi ìròyìn ìlàjì oṣù August sílẹ̀. Sọ fún wọn pé kí wọ́n má gbàgbé láti mú Ilé Ìṣọ́ September 1 àti Jí! July-September wá sí Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀, kí wọ́n sì múra sílẹ̀ láti ṣàlàyé àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tó máa bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu.

20 min: Aṣọ àti Ìmúra Wa Máa Ń Fògo Fún Jèhófà. Àsọyé tí alàgbà kan máa sọ. Torí pé Ọlọ́run mímọ́ ni Jèhófà, ìmọ́tótó ara ṣe pàtàkì láàárín àwa èèyàn rẹ̀. (Ẹ́kís. 30:17-21; 40:30-32) Bí aṣọ tá à ń wọ̀ àti ọ̀nà tá a gbà ń múra bá jẹ́ àpẹẹrẹ rere fáwọn èèyàn, àgàgà nígbà tá a bá wà lóde ẹ̀rí, inú Jèhófà á máa dùn sí wa, ìyẹn á sì máa fògo fún un. (1 Pét. 2:12) Àmọ́, tó bá jẹ́ pé aṣọ tí kò yẹ Kristẹni là ń wọ̀, ó lè jẹ́ ‘kí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di èyí táwọn èèyàn ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ tèébútèébú.’ (Títù 2:5) Sọ àwọn ìrírí kan tó ṣẹlẹ̀ ládùúgbò yín tàbí tó o kà nínú ìtẹ̀jáde wa, tó fi bí ìmúra akéde kan, tó jẹ́ àpẹẹrẹ rere, ṣe jẹ́rìí fáwọn èèyàn.

15 min: Àwọn Ọ̀dọ́ Tó Ń Fìtara Wàásù. Àsọyé tó ń gbéni ró tá a dìídì ṣètò fáwọn òbí àtàwọn ọmọ wọn tó máa tó padà síléèwé. Rán àwọn ọmọdé létí pé kí wọ́n lo gbogbo àǹfààní tí wọ́n bá ní láti wàásù. Bí àyè bá ṣe wà sí, ní káwọn ọ̀dọ́ sọ àwọn ìrírí tó dá lórí bí wọ́n ṣe wàásù níléèwé.

Orin 61

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 25

Orin 24

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́.

20 min: “Àwọn Àpéjọ Àgbáyé Ń Fògo fún Jèhófà.”b Tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí gbogbo wa máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ dáadáa tó bá dọ̀rọ̀ àwọn ohun tí ètò Ọlọ́run fẹ́ ká ṣe nígbà tá a bá ń múra sílẹ̀ fáwọn àpéjọ àgbáyé.

15 min: Múra Sílẹ̀ Láti Fi Ilé Ìṣọ́ September 1 àti Jí! July-September Lọni. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Sọ̀rọ̀ ṣókí nípa ìwé ìròyìn kọ̀ọ̀kan, kó o wá ní káwọn ará sọ àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣeé ṣe kó fa àwọn èèyàn lọ́kàn mọ́ra ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Àwọn ìbéèrè àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ni wọ́n lè fi nasẹ̀ ọ̀rọ̀. Ṣàṣefihàn bá a ṣe lè lo àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tá a dábàá nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Kí alàgbà kan tó ti múra sílẹ̀ dáadáa tún ṣàṣefihàn ṣókí lórí àpilẹ̀kọ kan tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu.

Orin 194

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 1

Orin 112

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù August sílẹ̀.

20 min: Wọn Ò Sí Láàárín Wa àmọ́ A Ò Gbàgbé Wọn. Àsọyé tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ April 15, 2008, ojú ìwé 25 sí 28. Dárúkọ àwọn akéde tó wà nínú ìjọ yín, àmọ́ tí wọn ò lè jáde nílé mọ́. Tírú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ò bá sí nínú ìjọ yín, lo àwọn ìlànà tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí láti gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n máa ran àwọn àláìlera lọ́wọ́, káwọn náà lè máa kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò ìjọ.

15 min: Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lójú Ẹsẹ̀ Lóṣù September. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni la máa lò lóde ẹ̀rí lóṣù September, a sì fẹ́ gbìyànjú láti ka ìpínrọ̀ bíi mélòó kan fáwọn tá a bá wàásù fún lọ́jọ́ àkọ́kọ́ tá a bá bá wọn sọ̀rọ̀. Ṣàyẹ̀wò àwọn àbá tó wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti March, 2006, kó o sì ṣàṣefihàn kan tàbí méjì tó dá lórí bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lójú ẹsẹ̀.

Orin 74

[Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́