ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/08 ojú ìwé 3-6
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run Ti Ọdún 2009

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run Ti Ọdún 2009
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Ìsọ̀rí
  • ÌTỌ́NI
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
km 10/08 ojú ìwé 3-6

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run Ti Ọdún 2009

ÌTỌ́NI

Èyí ni àlàyé lórí bí a ó ṣe máa darí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́dún 2009.

ÀWỌN ÌWÉ TÁ A MÁA LÒ NÍ ILÉ Ẹ̀KỌ́: Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun [bi12-YR], Ilé Ìṣọ́ [w-YR], Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà [lr-YR] àti “Àwọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bíbélì fún Ìjíròrò,” tó wà lẹ́yìn Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun (td-YR)

Ilé ẹ̀kọ́ gbọ́dọ̀ máa bẹ̀rẹ̀ LÁKÒÓKÒ. Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ ìkínikáàbọ̀, kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ ṣe àwọn ohun tá a là lẹ́sẹẹsẹ síbí yìí. Bí ẹnì kan bá ti ń parí iṣẹ́ tirẹ̀, kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ pe ẹni tó kàn sórí pèpéle.

ÀWỌN KÓKÓ PÀTÀKÌ LÁTINÚ BÍBÉLÌ: 10 min: Láàárín ìṣẹ́jú mẹ́rin àkọ́kọ́, kí alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó bá tóótun ṣàlàyé àwọn kókó inú Bíbélì kíkà ti ọ̀sẹ̀ yẹn. Àmọ́ bó bá jẹ́ pé orí ìwé Bíbélì tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ mú lọ́sẹ̀ yẹn ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ dá lé, kó mú ohun tó máa sọ láàárín ìṣẹ́jú mẹ́rin àkọ́kọ́ nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè” tó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ January 1, 2004. Bí àpẹẹrẹ, orí márùn-ún tó bẹ̀rẹ̀ ìwé Jẹ́nẹ́sísì la máa gbé yẹ̀ wò lọ́sẹ̀ January 5, torí náà kí ẹni tó niṣẹ́ yìí ṣe àṣàyàn àwọn kókó pàtàkì mélòó kan látinú Ilé Ìṣọ́ January 1, 2004 àti January 15, 2004, èyí tó jíròrò àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì. Kó sì jẹ́ káwọn ará rí bí àwọn kókó náà ṣe máa wúlò fún wọn. Ì báà jẹ́ kókó pàtàkì inú Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ló ń jíròrò ni o tàbí ó ń lo àpilẹ̀kọ inú Ilé Ìṣọ́, ohun pàtàkì tó gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn ni pé kó ran àwùjọ lọ́wọ́ láti rí ìdí tí wọ́n fi lè jàǹfààní látinú ọ̀rọ̀ tó ń sọ àti bí àǹfààní náà ṣe lè jẹ́ tiwọn. Kó rí i dájú pé òun ò lò kọjá ìṣẹ́jú mẹ́rin tó yẹ kó lò láti sọ apá tiẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ náà. Kó wá ya ìṣẹ́jú mẹ́fà tó kù sọ́tọ̀ fún àwùjọ láti sọ ohun tí wọ́n rí kọ́ nínú Bíbélì kíkà náà ní ṣókí, láàárín ààbọ̀ ìṣẹ́jú tàbí kó má tiẹ̀ tó bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ á wá sọ pé káwọn akẹ́kọ̀ọ́ tá a yàn sí kíláàsì mìíràn máa lọ síbẹ̀.

IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ 1: 4 min: (Ó sì lè máà tó ìṣẹ́jú mẹ́rin.) Èyí jẹ́ ìwé kíkà tá a máa yàn fún arákùnrin. Kí akẹ́kọ̀ọ́ ka ibi tá a yàn fún un láìsí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tàbí ọ̀rọ̀ àsọparí. Kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ fọwọ́ pàtàkì mú bó ṣe máa ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti kàwé lọ́nà tó yéni yékéyéké, lọ́nà tó já geere, pẹ̀lú ìtẹnumọ́ tó yẹ, yíyí ohùn pa dà, dídánudúró níbi tó yẹ àti sísọ̀rọ̀ bí Ọlọ́run ṣe dá wọn.

IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ 2: 5 min: Arábìnrin la ó máa yan iṣẹ́ yìí fún. A máa yan ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ kan fún arábìnrin tó niṣẹ́ yìí, òun fúnra rẹ̀ sì lè yan ọ̀kan lára àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tó wà lójú ìwé 82 nínú ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Kí akẹ́kọ̀ọ́ lo ẹṣin ọ̀rọ̀ tá a yàn fún un, kó sì lò ó lọ́nà tó máa bá onírúurú ọ̀nà tá a gbà ń wàásù ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ mu. Bí a ò bá kọ ibi tá a ti mú iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ yìí jáde síwájú iṣẹ́ náà, kí akẹ́kọ̀ọ́ lọ ṣèwádìí nínú àwọn ìwé wa láti lè mọ ohun tó máa sọ. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ á fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀nà tí akẹ́kọ̀ọ́ gbà ṣàlàyé ọ̀rọ̀ rẹ̀, bó ṣe mú kí onílé ronú lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó kà àti bó ṣe mú kó lóye àwọn kókó pàtàkì inú iṣẹ́ rẹ̀. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ máa yan olùrànlọ́wọ́ kan fún akẹ́kọ̀ọ́ náà.

IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ 3: 5 min: Arákùnrin tàbí arábìnrin la ó máa yan iṣẹ́ yìí fún. Ẹṣin ọ̀rọ̀ tó wà fún iṣẹ́ yìí ni kí akẹ́kọ̀ọ́ ṣiṣẹ́ lé lórí. Bá ò bá kọ ibi tá a ti mú iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ yìí jáde síwájú iṣẹ́ náà, kí akẹ́kọ̀ọ́ lọ ṣèwádìí nínú àwọn ìwé wa. Bá a bá yan iṣẹ́ yìí fún arákùnrin, kó sọ ọ́ bí àsọyé, kó sì darí ẹ̀ sí àwùjọ. Bó bá jẹ́ arábìnrin ló máa bójú tó o, kó tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà fún Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ 2. Jọ̀wọ́, kíyè sí i pé, bá a bá sàmì ìràwọ̀ (*) síwájú ẹṣin ọ̀rọ̀ èyíkéyìí, àwọn arákùnrin ni ká yàn án fún kí wọ́n lè sọ ọ́ bí àsọyé. Nígbàkigbà tó bá sì jẹ́ pé alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ló máa dáa jù kó ṣe iṣẹ́ náà, a lè gbé e fún wọn.

ÌMỌ̀RÀN: 1-2 min: Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ ò ní máa sọ ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ tí akẹ́kọ̀ọ́ máa ṣiṣẹ́ lé lórí fún àwùjọ. Lẹ́yìn Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ 1, 2 àti 3, kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ sọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró lórí ohun kan tó kíyè sí pé ó dára nínú iṣẹ́ náà, kó sì ṣàlàyé ìdí pàtó tí ohun tó kíyè sí nínú iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà fi wúlò. Kó máa lo ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lemọ́lemọ́ láti ti ohun tó ń sọ lẹ́yìn. Bó bá kíyè sí i pé iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ kan kù síbì kan, bí ìpàdé bá parí tàbí nígbà míì, kó fún un nímọ̀ràn tó máa mú kó tẹ̀ síwájú.

ÀKÓKÒ: Akẹ́kọ̀ọ́ kankan kò gbọ́dọ̀ kọjá àkókò, kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ náà má sì ṣe sọ̀rọ̀ kọjá àkókò. Ọgbọ́n la ó máa fi dá Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ 1 sí 3 dúró bí àkókò wọn bá ti pé. Bí àwọn arákùnrin tó ń bójú tó àwọn kókó pàtàkì látinú Bíbélì bá kọjá àkókò, fún wọn ní ìmọ̀ràn ní ìdákọ́ńkọ́. Kí gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ rí i pé àwọn ò kọjá àkókò. Àkókò tá ó fi darí Ilé Ẹ̀kọ́: 30 ìṣẹ́jú, bá a bá yọ orin àti àdúrà.

ÌWÉ ÌMỌ̀RÀN Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ: Èyí wà nínú ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run.

OLÙRÀNLỌ́WỌ́ AGBANI-NÍMỌ̀RÀN: Bí alàgbà kan tó tóótun bá wà, ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà lè yàn án pé kó máa ran alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn. Bí àwọn alàgbà bá pọ̀ nínú ìjọ, a lè máa lo alàgbà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó tóótun lọ́dọọdún. Ojúṣe olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn ni láti máa fún àwọn arákùnrin tó ń bójú tó kókó pàtàkì látinú Bíbélì nímọ̀ràn ní ìdákọ́ńkọ́, bó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Kò pọn dandan kó jẹ́ pé gbogbo ìgbà táwọn alàgbà bíi tiẹ̀ àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ bá bójú tó àwọn iṣẹ́ yìí lá máa gbà wọ́n nímọ̀ràn.

ÀTÚNYẸ̀WÒ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ÌJỌBA ỌLỌ́RUN: 20 min: Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ á máa darí àtúnyẹ̀wò lóṣù méjì-méjì. Ṣáájú èyí, a óò gbọ́ àwọn kókó pàtàkì látinú Bíbélì, bá a ṣe ṣàlàyé lókè. Àwọn kókó tá a jíròrò ní ilé ẹ̀kọ́ láàárín oṣù méjì sí àkókò yẹn, títí kan ti ọ̀sẹ̀ yẹn gan-an ni àtúnyẹ̀wò náà máa dá lé. Bí àpéjọ àyíká yín tàbí ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká bá bọ́ sí ọ̀sẹ̀ Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ẹ sún àtúnyẹ̀wò náà sí ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, kẹ́ ẹ wá ṣe Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ 1 sí 3 tó wà fún ọ̀sẹ̀ tẹ́ ẹ sún àtúnyẹ̀wò sí yẹn. Ẹ má ṣe yí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó wà fún Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ tàbí àwọn kókó pàtàkì látinú Bíbélì pa dà o.

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ

Jan. 5 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 1-5

No. 1: Jẹ́nẹ́sísì 3:1-15

No. 2: Ohun Tó Mú Kí Jésù Jẹ́ Olùkọ́ Ńlá (lr orí 1)

No. 3: Kí Ni Kì Í Ṣe Asán? (1 Kọ́r. 15:58)

Jan. 12 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 6-10

No. 1: Jẹ́nẹ́sísì 9:1-17

No. 2: Kí Ni Ẹ̀ṣẹ̀ Lòdì sí Ẹ̀mí Mímọ́? (td-YR 15E)

No. 3: Lẹ́tà Kan Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Tó Fẹ́ràn Wa (lr orí 2)

Jan. 19 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 11-16

No. 1: Jẹ́nẹ́sísì 14:1-16

No. 2: Ẹni Tí Ó Dá Ohun Gbogbo (lr orí 3)

No. 3: Báwo Ni Jèhófà Ṣe Ń Mọ Wá? (Aísá. 64:8)

Jan. 26 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 17-20

No. 1: Jẹ́nẹ́sísì 17:1-17

No. 2: Kí Ni Ọkàn? (td-YR 40A)

No. 3: Ọlọ́run Ní Orúkọ Kan (lr orí 4)

Feb. 2 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 21-24

No. 1: Jẹ́nẹ́sísì 22:1-18

No. 2: “Èyí Ni Ọmọ Mi” (lr orí 5)

No. 3: a Àwọn Ọ̀nà Tá A Lè Gbà Máa Fìfẹ́ Hàn Sáwọn Èèyàn (2 Kọ́r. 6:11-13)

Feb. 9 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 25-28

No. 1: Jẹ́nẹ́sísì 25:1-18

No. 2: Olùkọ́ Ńlá Náà Sin Àwọn Ẹlòmíràn (lr orí 6)

No. 3: Kí Ni Ìyàtọ̀ Tó Wà Láàárín Ọkàn àti Ẹ̀mí? (td-YR 40B)

Feb. 16 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 29-31

No. 1: Jẹ́nẹ́sísì 29:1-20

No. 2: Ìdí Tó Fi Yẹ Ká “Dẹ́kun Ṣíṣàníyàn” (Mát. 6:25)

No. 3: Ìgbọràn Ń Dáàbò Bò Ọ́ (lr orí 7)

Feb. 23 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 32-35

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Mar. 2 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 36-39

No. 1: Jẹ́nẹ́sísì 39:1-16

No. 2: Àwọn Kan Wà Nípò Tó Ga Ju Tiwa Lọ (lr orí 8)

No. 3: Kí Ni Ẹ̀mí Mímọ́? (td-YR 13A)

Mar. 9 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 40-42

No. 1: Jẹ́nẹ́sísì 40:1-15

No. 2: A Gbọ́dọ̀ Kọ Ìdẹwò (lr orí 9)

No. 3: b Ṣọ́ra fún Ẹ̀mí Tinú-Mi-Ni-Màá-Ṣe!

Mar. 16 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 43-46

No. 1: Jẹ́nẹ́sísì 44:1-17

No. 2: Agbára Jésù Ju Ti Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Lọ (lr orí 10)

No. 3: Ipá Ìwàláàyè Èèyàn àti Ti Ẹranko Ló Ń Jẹ́ Ẹ̀mí (td-YR 13B)

Mar. 23 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 47-50

No. 1: Jẹ́nẹ́sísì 48:1-16

No. 2: Ṣó Yẹ Ká Máa Bẹ̀rù Èṣù?

No. 3: Ìrànlọ́wọ́ Látọ̀dọ̀ Àwọn Áńgẹ́lì Ọlọ́run (lr orí 11)

Mar. 30 Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 1-6

No. 1: Ẹ́kísódù 1:1-19

No. 2: Jésù Kọ́ Wa Bí A Ó Ṣe Máa Gbàdúrà (lr orí 12)

No. 3: Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Kọ Gbogbo Onírúurú Ìbẹ́mìílò Sílẹ̀? (td-YR 13D)

Apr. 6 Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 7-10

No. 1: Ẹ́kísódù 9:1-19

No. 2: Àwọn Tó Di Ọmọ Ẹ̀yìn Jésù (lr orí 13)

No. 3: c Báwo La Ṣe Lè Fi Hàn Pé Gálátíà 6:2 àti Gálátíà 6:5 Kò Ta Kora?

Apr. 13 Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 11-14

No. 1: Ẹ́kísódù 12:21-36

No. 2: Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Dárí Jini (lr orí 14)

No. 3: Ìdí Tí Jèhófà Ò Fi Lè Jẹ́ Apá Kan Mẹ́talọ́kan (td-YR 36A)

Apr. 20 Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 15-18

No. 1: Ẹ́kísódù 15:1-19

No. 2: Àwọn Ọ̀nà Wo Lèèyàn Lè Gbà Yẹra fún Ẹ̀sìn Èké?

No. 3: Ẹ̀kọ́ Nípa Jíjẹ́ Onínúure (lr orí 15)

Apr. 27 Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 19-22

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

May 4 Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 23-26

No. 1: Ẹ́kísódù 24:1-18

No. 2: Kí Ni Ó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ? (lr orí 16)

No. 3: Ọmọ Ò Bá Baba Dọ́gba (td-YR 36B)

May 11 Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 27-29

No. 1: Ẹ́kísódù 29:1-18

No. 2: Bí A Ṣe Lè Ní Ayọ̀ (lr orí 17)

No. 3: d Èrò Tí Kò Tọ́ Nípa Ìdúróṣinṣin Àtàwọn Ewu Tó Rọ̀ Mọ́ Ọn

May 18 Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 30-33

No. 1: Ẹ́kísódù 31:1-18

No. 2: Bí Ọlọ́run àti Kristi Ṣe Jẹ́ Ọ̀kan (td-YR 36D)

No. 3: Ǹjẹ́ O Máa Ń Rántí Láti Dúpẹ́? (lr orí 18)

May 25 Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 34-37

No. 1: Ẹ́kísódù 37:1-24

No. 2: Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Máa Jà? (lr orí 19)

No. 3: e Kí Ni Ìgbọ̀jẹ̀gẹ́, Kí sì Nìdí Tí Kò Fi Yẹ Ká Máa Gbọ̀jẹ̀gẹ́?

June 1 Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 38-40

No. 1: Ẹ́kísódù 40:1-19

No. 2: Ǹjẹ́ O Máa Ń Fẹ́ Jẹ́ Ẹni Àkọ́kọ́ Nígbà Gbogbo? (lr orí 20)

No. 3: Ẹ̀mí Mímọ́ Kì Í Ṣe Ẹnì Kan (td-YR 36E)

June 8 Bíbélì kíkà: Léfítíkù 1-5

No. 1: Léfítíkù 4:1-15

No. 2: Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Máa Fọ́nnu? (lr orí 21)

No. 3: f Báwo Ló Ṣe Yẹ Káwọn Kristẹni Máa Lo Ọlá Àṣẹ?

June 15 Bíbélì kíkà: Léfítíkù 6-9

No. 1: Léfítíkù 8:1-17

No. 2: Ọlọ́run Kọ́ Ló Fa Wàhálà Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Ayé (td-YR 31A)

No. 3: Ìdí Tí Kò Fi Yẹ Ká Máa Purọ́ (lr orí 22)

June 22 Bíbélì kíkà: Léfítíkù 10-13

No. 1: Léfítíkù 11:29-45

No. 2: Ìdí Tí Àwọn Èèyàn Fi Ń Ṣàìsàn (lr orí 23)

No. 3: Ìbùkún Táwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Tó Ti Ṣèrìbọmi Ń Gbádùn

June 29 Bíbélì kíkà: Léfítíkù 14-16

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

July 6 Bíbélì kíkà: Léfítíkù 17-20

No. 1: Léfítíkù 19:1-18

No. 2: Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìwà Burúkú (td-YR 31B)

No. 3: Má Ṣe Di Olè! (lr orí 24)

July 13 Bíbélì kíkà: Léfítíkù 21-24

No. 1: Léfítíkù 22:17-33

No. 2: Ǹjẹ́ Àwọn Tó Ń Ṣe Ohun Búburú Lè Yí Padà? (lr orí 25)

No. 3: Báwọn Kristẹni Tòótọ́ Ṣe Ń Ṣàánú Fáwọn Tálákà

July 20 Bíbélì kíkà: Léfítíkù 25-27

No. 1: Léfítíkù 25:39-54

No. 2: Ìdí Tó Fi Nira Láti Máa Ṣe Rere (lr orí 26)

No. 3: Ọlọ́run Fi Àánú Rẹ̀ Hàn (td-YR 31D)

July 27 Bíbélì kíkà: Númérì 1-3

No. 1: Númérì 3:1-20

No. 2: Ìdí Tó Fi Gba Ìkóra-Ẹni-Níjàánu Kéèyàn Tó Lè Jẹ́ Oníwà Tútù

No. 3: Ta Ni Ọlọ́run Rẹ? (lr orí 27)

Aug. 3 Bíbélì kíkà: Númérì 4-6

No. 1: Númérì 4:1-16

No. 2: Bí A Ṣe Lè Mọ Ẹni Tó Yẹ Kí Á Ṣègbọràn Sí (lr orí 28)

No. 3: Ìjọba Ọlọ́run Nìkan Ló Lè Yanjú Ìṣòro Aráyé (td-YR 31E)

Aug. 10 Bíbélì kíkà: Númérì 7-9

No. 1: Númérì 9:1-14

No. 2: Ǹjẹ́ Gbogbo Àpèjẹ Ni Inú Ọlọ́run Dùn Sí? (lr orí 29)

No. 3: Àwọn Ọ̀nà Tá A Lè Gbà Fi Hàn Pé A Dúró Ṣinṣin Ti Jèhófà

Aug. 17 Bíbélì kíkà: Númérì 10-13

No. 1: Númérì 13:17-33

No. 2: Ìrànlọ́wọ́ Láti Borí Ìbẹ̀rù (lr orí 30)

No. 3: Gbogbo Kristẹni Tòótọ́ Gbọ́dọ̀ Jẹ́rìí sí Òtítọ́ (td-YR 20A)

Aug. 24 Bíbélì kíkà: Númérì 14-16

No. 1: Númérì 14:26-43

No. 2: Kí Ló Túmọ̀ sí Láti Nífẹ̀ẹ́ Òfin Ọlọ́run? (Sm. 119:97)

No. 3: Ibi Tí A Ti Lè Rí Ìtùnú Gbà (lr orí 31)

Aug. 31 Bíbélì kíkà: Númérì 17-21

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Sept. 7 Bíbélì kíkà: Númérì 22-25

No. 1: Númérì 22:20-35

No. 2: Bí Ọlọ́run Ṣe Dáàbò Bo Jésù (lr orí 32)

No. 3: Ìdí Tá A Fi Ń Bẹ Àwọn Èèyàn Wò Léraléra (td-YR 20B)

Sept. 14 Bíbélì kíkà: Númérì 26-29

No. 1: Númérì 27:1-14

No. 2: Kí Ni Ìlànà Èrò Orí, Kí sì Nìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì? (Éfé. 6:4)

No. 3: Jésù Lè Dáàbò Bò Wá (lr orí 33)

Sept. 21 Bíbélì kíkà: Númérì 30-32

No. 1: Númérì 32:1-15

No. 2: Kí Ni Yóò Ṣẹlẹ̀ Bí A Bá Kú? (lr orí 34)

No. 3: Bá A Bá Ń Jẹ́rìí A Ò Ní Jẹ̀bi Ẹ̀jẹ̀ (td-YR 20D)

Sept. 28 Bíbélì kíkà: Númérì 33-36

No. 1: Númérì 33:1-23

No. 2: A Lè Jí Dìde Kúrò Nínú Ikú! (lr orí 35)

No. 3: Àwọn Ọ̀nà Tí Ìjọba Ọlọ́run Fi Dára Ju Ìjọba Èèyàn Lọ

Oct. 5 Bíbélì kíkà: Diutarónómì 1-3

No. 1: Diutarónómì 2:1-15

No. 2: Ìdí Tí Inú Ọlọ́run Ò Fi Dùn sí Jíjọ́sìn Àwọn Baba Ńlá (td-YR 22A)

No. 3: Àwọn Wo Ni A Óò Jí Dìde? Ibo Ni Wọn Yóò Máa Gbé? (lr orí 36)

Oct. 12 Bíbélì kíkà: Diutarónómì 4-6

No. 1: Diutarónómì 4:15-28

No. 2: Bí A Ṣe Lè Rántí Jèhófà àti Ọmọ Rẹ̀ (lr orí 37)

No. 3: Ìgbà Wo La Lè Sọ Pé Díẹ̀ Sàn Jù? (Òwe 15:16)

Oct. 19 Bíbélì kíkà: Diutarónómì 7-10

No. 1: Diutarónómì 9:1-14

No. 2: Ìdí Tó Fi Yẹ Kí Á Fẹ́ràn Jésù (lr orí 38)

No. 3: A Lè Bọlá fún Ẹ̀dá Èèyàn, Àmọ́ Ọlọ́run Nìkan La Gbọ́dọ̀ Jọ́sìn (td-YR 22B)

Oct. 26 Bíbélì kíkà: Diutarónómì 11-13

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Nov. 2 Bíbélì kíkà: Diutarónómì 14-18

No. 1: Diutarónómì 15:1-15

No. 2: Kí Ni Ìbẹ̀rù Ọlọ́run Túmọ̀ Sí?

No. 3: Ọlọ́run Rántí Ọmọ Rẹ̀ (lr orí 39)

Nov. 9 Bíbélì kíkà: Diutarónómì 19-22

No. 1: Diutarónómì 22:1-19

No. 2: Bí A Ṣe Lè Mú Inú Ọlọ́run Dùn (lr orí 40)

No. 3: Amágẹ́dọ́nì Logun Tí Ọlọ́run Máa Lò Láti Fòpin sí Ìwà Burúkú (td-YR 4A)

Nov. 16 Bíbélì kíkà: Diutarónómì 23-27

No. 1: Diutarónómì 25:1-16

No. 2: Àwọn Ọmọdé Tó Mú Inú Ọlọ́run Dùn (lr orí 41)

No. 3: g Àwọn Nǹkan Wo Ló Yẹ Ká Kà sí Mímọ́?

Nov. 23 Bíbélì kíkà: Diutarónómì 28-31

No. 1: Diutarónómì 30:1-14

No. 2: Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Ṣiṣẹ́ (lr orí 42)

No. 3: Ìdí Tí Amágẹ́dọ́nì Fi Jẹ́ Ẹ̀rí Pé Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Wa (td-YR 4B)

Nov. 30 Bíbélì kíkà: Diutarónómì 32-34

No. 1: Diutarónómì 32:1-21

No. 2: Kí Ni “Ọjọ́ Ńlá Jèhófà”? (Sef. 1:14)

No. 3: Àwọn Wo Ni Arákùnrin àti Arábìnrin Wa? (lr orí 43)

Dec. 7 Bíbélì kíkà: Jóṣúà 1-5

No. 1: Jóṣúà 5:1-15

No. 2: Ó Yẹ Kí Àwọn Ọ̀rẹ́ Wa Fẹ́ràn Ọlọ́run (lr orí 44)

No. 3: Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run? Bí A Ṣe Lè Fi Hàn Pé À Ń Fẹ́ Ẹ (lr orí 45)

Dec. 14 Bíbélì kíkà: Jóṣúà 6-8

No. 1: Jóṣúà 8:1-17

No. 2: Omi Pa Ayé Kan Run—Ǹjẹ́ Irú Ẹ̀ Tún Lè Ṣẹlẹ̀ Mọ́? (lr orí 46)

No. 3: Kí Nìdí Tí Ìmọ̀ràn Inú Oníwàásù 7:21, 22 Fi Wúlò?

Dec. 21 Bíbélì kíkà: Jóṣúà 9-11

No. 1: Jóṣúà 9:1-15

No. 2: Bí A Ṣe Lè Mọ̀ Pé Amágẹ́dọ́nì Ti Sún Mọ́lé (lr orí 47)

No. 3: Ayé Tuntun Ọlọ́run, Ayé Àlàáfíà —Ìwọ Lè Wà Níbẹ̀ (lr orí 48)

Dec. 28 Bíbélì kíkà: Jóṣúà 12-15

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

[Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé]

a Àwọn arákùnrin nìkan ni ká yan iṣẹ́ yìí fún, ó sàn kí wọ́n jẹ́ alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.

b Àwọn arákùnrin nìkan ni ká yan iṣẹ́ yìí fún, ó sàn kí wọ́n jẹ́ alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.

c Àwọn arákùnrin nìkan ni ká yan iṣẹ́ yìí fún, ó sàn kí wọ́n jẹ́ alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.

d Àwọn arákùnrin nìkan ni ká yan iṣẹ́ yìí fún, ó sàn kí wọ́n jẹ́ alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.

e Àwọn arákùnrin nìkan ni ká yan iṣẹ́ yìí fún, ó sàn kí wọ́n jẹ́ alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.

f Àwọn arákùnrin nìkan ni ká yan iṣẹ́ yìí fún, ó sàn kí wọ́n jẹ́ alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.

g Àwọn arákùnrin nìkan ni ká yan iṣẹ́ yìí fún, ó sàn kí wọ́n jẹ́ alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́