ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/08 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 8
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 15
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 22
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 29
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 5, 2009
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
km 12/08 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 8

Orin 19

15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Jíròrò “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká Tuntun.” Sọ ọjọ́ tí àpéjọ àyíká yín máa bọ́ sí, tá a bá ti fi ránṣẹ́ sí yín. Ní ṣókí, sọ̀rọ̀ lórí àbá tó wà lójú ìwé 8 nípa bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ December 1 àti Jí! January-March. Ní káwọn tó ti lo ìwé ìròyìn yìí lọ́nà tó gbéṣẹ́ sọ ọ̀nà tí wọ́n gbà ṣe é. Kí wọ́n sọ àpilẹ̀kọ, ìbéèrè àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lò.

15 min: Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ti Ọdún 2009. Àsọyé tí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ máa sọ. Lo àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 2008 láti fi jíròrò àwọn kókó tó bá ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ yín. Ṣàlàyé ojúṣe olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn. Fún àwọn ará níṣìírí láti má fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ tá a bá yàn fún wọn, kí wọ́n máa lóhùn sí Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, kí wọ́n sì máa fi àwọn àbá tí wọ́n bá rí gbà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ látinú ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run sílò.

15 min: “Ṣé Ò Ń Lo Ìwé Náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó?”a Tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 4, ní kí aṣáájú ọ̀nà kan tàbí àkéde míì tó bá tóótun ṣàṣefihàn ṣókí nípa bó ṣe máa lo Àwọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bíbélì fún Ìjíròrò tó wà lójú ìwé 1840 sí 1853 lẹ́yìn Bíbélì wa, lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé láti dáhùn ìbéèrè náà, ‘Kí nìdí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi í ṣayẹyẹ Kérésìmesì?’

Orin 6

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 15

Orin 178

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù December sílẹ̀. Àwọn ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.

10 min: Sísọ Àsọtúnsọ Lóde Ẹ̀rí. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka Ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ojú ìwé 207. Ní ṣókí, ṣàṣefihàn kan tàbí méjì látinú ìwé náà.

25 min: “‘Jẹ́rìí Kúnnákúnná’ Nígbà Tó O Bá Ń Wàásù Nílé Elérò Púpọ̀.”b Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn tàbí alàgbà míì ni kó bójú tó o. Sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu. Bí kò bá sí àwọn ilé elérò púpọ̀ ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín, kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn tàbí alàgbà míì sọ àsọyé tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ January 1, 2005, ojú ìwé 13 sí 17, ìpínrọ̀ 8 sí 24 gẹ́gẹ́ bí àfidípò.

Orin 157

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 22

Orin 75

15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Jíròrò “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àkànṣe Tuntun.” Sọ ọjọ́ tí àpéjọ àkànṣe yín máa bọ́ sí, tá a bá ti fi ránṣẹ́ sí yín. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́. Sọ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a máa lò lóṣù January, kó o sì jẹ́ kí alàgbà kan ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lò ó.

15 min: Múra Sílẹ̀ Láti Lo Ilé Ìṣọ́ January 1 àti Jí! January-March. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Lẹ́yìn tó o bá ti sọ̀rọ̀ ṣókí lórí àwọn ìwé ìròyìn yìí, ní káwọn ará sọ àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣeé ṣe kó fa àwọn èèyàn lọ́kàn mọ́ra ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, kí wọ́n sì sọ ìdí tí wọ́n fi rò bẹ́ẹ̀. Ní kí wọ́n mẹ́nu ba àwọn kókó kan látinú àwọn àpilẹ̀kọ tí wọ́n ní lọ́kàn láti lò lóde ẹ̀rí. Ìbéèrè wo ni wọ́n lè fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò? Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ni wọ́n máa fẹ́ kà látinú àpilẹ̀kọ náà? Níparí ọ̀rọ̀ rẹ, lo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a dábàá lójú ìwé 8 tàbí àwọn míì tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo ìwé ìròyìn kọ̀ọ̀kan.

15 min: “Ọjọ́ Tá A Yà Sọ́tọ̀ Láti Máa Fi Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ Àwọn Èèyàn.”c Sọ òpin ọ̀sẹ̀ tí ìjọ yín á lò láti fi bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lóṣù January. Sọ̀rọ̀ lórí àbá tó wà ní ìpínrọ̀ 3, kó o sì ṣe àṣefihàn kan tàbí méjì lórí bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Orin 133

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 29

Orin 60

Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:

jd orí 12 ìpínrọ̀ 1 sí 10

Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:

Bíbélì kíkà: Ìṣípayá 15-22

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:

Orin 153

5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù December sílẹ̀.

10 min: Àpótí Ìbéèrè. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ.

20 min: “Iṣẹ́ Ìwàásù Gba Ìfaradà.”d Bí àyè bá ṣe wà sí, ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí.

Orin 155

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 5, 2009

Orin 35

Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:

jd orí 12 ìpínrọ̀ 11 sí 22

Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:

Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 1-5.

No. 1: Jẹ́nẹ́sísì 3:1-15

No. 2: Ohun Tó Mú Kí Jésù Jẹ́ Olùkọ́ Ńlá (lr-YR orí 1)

No. 3: Kí Ni Kì Í Ṣe Asán? (1 Kọ́r. 15:58)

Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:

Orin 98

5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

10 min: Irú Ọwọ́ Tí Jésù Fi Mú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ni Kíwọ Náà fi Mú Un. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ, tá a gbé ka ìwé “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn,” ojú ìwé 84 sí 86, ìpínrọ̀ 16 sí 21.

20 min: “A Máa Pín Ìwé Àṣàrò Kúkúrú Lákànṣe ní January 19 sí February 15, 2009!”e Bí ìwé àṣàrò kúkúrú náà bá ti tẹ̀ yín lọ́wọ́, fún àwọn ará ní ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan. Ní ṣókí, sọ àwọn kókó ẹ̀kọ́ inú ìwé àṣàrò kúkúrú náà nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 2. Bó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 4, ṣàṣefihàn bá a ṣe lè lo ìwé àṣàrò kúkúrú náà. Bó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 5, ṣàṣefihàn kan nípa bí akéde kan ṣe lo ìwé àṣàrò kúkúrú náà láti fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà tó lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò.

Orin 114

[Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

e Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́