Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ April 13
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ APRIL 13
Orin 38
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
lv-YR àfikún ẹ̀yìn ìwé, ojú ìwé 207 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 209 ìpínrọ̀ 3
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 11-14
No. 1: Ẹ́kísódù 12:21-36
No. 2: Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Dárí Jini (lr orí 14)
No. 3: Ìdí Tí Jèhófà Ò Fi Lè Jẹ́ Apá Kan Mẹ́talọ́kan (td-YR 36A)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 125
5 min: Àwọn ìfilọ̀. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù April sílẹ̀.
10 min: Sọ̀rọ̀ lórí bí ọjọ́ àkànṣe tá a yà sọ́tọ̀ fún fífi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ àwọn èèyàn ṣe ń tẹ̀ síwájú sí. Sọ ìrírí kan tàbí méjì.
10 min: Lo Ọgbọ́n Nígbà Tó O Bá Ń Wàásù. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ, tó dá lórí ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 197 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 200 ìpínrọ̀ 1. Ṣàṣefihàn bí àkéde kan ṣe lè fèsì bí onílé kan bá sọ nǹkan táwọn tí kì í fẹ́ gbọ́ ìwàásù sábà máa ń sọ.
10 min: “Iṣẹ́ Ìwàásù Máa Ń Jẹ́ Ká Lókun Nípa Tẹ̀mí.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
Orin 5