Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ June 29
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JUNE 29
Orin 124
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Léfítíkù 14-16
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 81
5 min: Àwọn ìfilọ̀. Rán àwọn ará létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù June sílẹ̀.
10 min: Kí Nìdí Tí Ìrísí Tó Dára Fi Ṣe Pàtàkì? Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tó dá lórí ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 131 sí 134.
10 min: Yan Ọ̀rọ̀ Tó Dá Lórí Bíbélì fún “Ènìyàn Gbogbo.” (1 Kọ́r. 9:22) Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Tẹ́ ẹ bá ń jíròrò àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí, jẹ́ kí àwùjọ sọ àwọn ìrírí táwọn fúnra wọn ní. Àwọn ọ̀nà wo lo ti gbà gbé ọ̀rọ̀ rẹ kalẹ̀ tó o sì rí i pé ó sábà máa ń wọ àwọn kan lọ́kàn, bóyá àwọn tó wà ní ọjọ́ orí kan pàtó, ọkùnrin, obìnrin tàbí àwọn ẹlẹ́sìn kan? Báwo lo ṣe lè lo Àwọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bíbélì fún Ìjíròrò láti yan àwọn àkòrí ọ̀rọ̀ tó máa fa onírúurú èèyàn mọ́ra? Báwo la ṣe lè mọwọ́ yí pa dà?
10 min: Ìwé Tá A Máa Lò Lóṣù July àti August. Sọ àwọn kókó ẹ̀kọ́ tó wà nínú àwọn ìwé náà, kó o sì ṣe àṣefihàn méjì tàbí mẹ́ta tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu.
Orin 215