Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Àmúlùmálà Ìgbàgbọ́ Níléèwé
1. (a) Kí ló mú káwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa hùwà ọmọlúwàbí? (b) Àwọn ìṣòro wo ni wọ́n máa ń dojú kọ?
1 Ní ọ̀pọ̀ ilé ẹ̀kọ́, wọ́n mọ̀ pé àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ọmọlúwàbí. Ìdí ni pé àwọn òbí wọn ti sapá gidigidi láti ‘tọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.’ (Éfé. 6:4) Síbẹ̀, wọ́n máa ń dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro níléèwé. A máa ń gbọ́ dáadáa pé àwọn ọmọ iléèwé ń ṣèṣekúṣe wọ́n sì ń hùwà ipá níléèwé.
2. Kí làwọn aláṣẹ iléèwé kan máa ń ṣe láti ki ọwọ́ ìwàkiwà bọlẹ̀?
2 Káwọn aláṣẹ ilé ìwé bàa lè ki ọwọ́ ìwàkiwà tó ń pọ̀ sí i níléèwé bọlẹ̀, wọ́n máa ń kọ́ àwọn ọmọléèwé lẹ́kọ̀ọ́ ìsìn, wọ́n sì máa ń pe àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì wá nígbà míì láti wá kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Àwọn ilé ìwé kan máa ń gbàdúrà níbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Wọ́n máa ń kọrin ẹ̀sìn tí wọ́n bá péjọ láràárọ̀. Kódà wọ́n tún máa ń kọ́ àwọn ọmọ lẹ́kọ̀ọ́ èké àtàwọn orin ẹ̀sìn nínú kíláàsì. Àwọn aláṣẹ iléèwé máa ń jẹ́ kó dà bíi pé dandan ni káwọn ọmọléèwé lọ́wọ́ sí àwọn ààtò ẹ̀sìn àtàwọn ayẹyẹ wọ̀nyí, wọ́n sì lè ní kí wọ́n má ṣe wá síléèwé fáwọn àkókò kan tàbí kí wọ́n lé wọn kúrò pátápátá bí wọ́n bá kọ̀ láti bá wọn lọ́wọ́ sí i.
3. Kí ló yẹ kó jẹ gbogbo òbí lógún?
3 Ojúṣe àwọn òbí Kristẹni ló jẹ́ láti máa dáàbò bo àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ irú àwọn àmúlùmálà ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi máa ń fáwọn ọmọ ní ìtọ́ni látinú Ìwé Mímọ́ kí wọ́n bàa lè ta kété sí Bábílónì Ńlá kí wọ́n má sì “ṣàjọpín pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,” kí wọ́n sì “jáwọ́ nínú fífọwọ́kan ohun àìmọ́.” (Ìṣí. 18:4; 2 Kọ́r. 6:14-18) A gbóríyìn fún gbogbo ẹ̀yin òbí tẹ́ ẹ̀ ń fi hàn pé ipò tẹ̀mí àwọn ọmọ yín jẹ yín lógún. Àwọn nǹkan míì wo lẹ̀yin òbí lè ṣe láti dáàbò bo àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ “elénìní” tó ń dìídì dájú sọ àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn tí ò fi bẹ́ẹ̀ nírìírí yìí?—1 Pét. 5:7, 8.
4. Ìgbà wo ló yẹ kẹ́yin òbí bá àwọn olùkọ́ àwọn ọmọ yín jíròrò?
4 Ó ṣe pàtàkì pé kẹ́yin òbí ti jíròrò ìwé pẹlẹbẹ náà Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́, pẹ̀lú àwọn aláṣẹ iléèwé àtàwọn olùkọ́ àwọn ọmọ yín kó tiẹ̀ tó di pé ìṣòro yọjú rárá. Lẹ́yìn náà, ẹ̀yin òbí tún lè fún wọn ní lẹ́tà tó ṣàlàyé ohun tẹ́ ẹ gbà gbọ́. Kí lẹ́tà náà ṣe kedere, kó rọrùn, kẹ́ ẹ sì kọ ọ́ lọ́nà tó fọ̀wọ̀ hàn.
5. Àwọn àǹfààní wo làwọn òbí máa jẹ tí wọ́n bá sapá gidigidi láti dáàbò bo àwọn ọmọ wọn?
5 Torí pé ayé yìí fẹ́ sọ àwọn èèyàn dà bó ṣe dà, a mọ̀ pé ìdánwò ìgbàgbọ́ táwọn ọmọ wa máa dojú kọ níléèwé máa pọ̀ sí i. (Róòmù 12:2) Ó dá wa lójú pé ẹ̀yin òbí máa jẹ́ ọlọgbọ́n nípa gbígbé ìgbésẹ̀ láti dáàbò bo àwọn ọmọ yín tí ò nírìírí kí wọ́n má bàa kàgbákò nípa tẹ̀mí. (Òwe 22:3) Ó dájú pé Jèhófà máa tì yín lẹ́yìn bẹ́ ẹ ṣe ń sapá láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti máa tọ ọ̀nà tóóró tó lọ sí ìyè.—Mát. 7:13, 14.