Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ October 5
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ OCTOBER 5
Orin 173
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Diutarónómì 1-3
No. 1: Diutarónómì 2:1-15
No. 2: Ìdí Tí Inú Ọlọ́run Ò Fi Dùn sí Jíjọ́sìn Àwọn Baba Ńlá (td-YR 22A)
No. 3: Àwọn Wo Ni A Óò Jí Dìde? Ibo Ni Wọn Yóò Máa Gbé? (lr orí 36)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 42
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
15 min: Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́? Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ní káwọn ará sọ èyí tó ń fa àwọn èèyàn mọ́ra jù lọ nínú àwọn ìbéèrè tó wà nínú ìwé àṣàrò kúkúrú náà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Ṣàṣefihàn bá a ṣe lè lo ìwé àṣàrò kúkúrú náà láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
15 min: “Ṣọ́ra fún ‘Àwọn Èké Arákùnrin.’” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
Orin 100