Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ November 9
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ NOVEMBER 9
Orin 145
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Diutarónómì 19-22
No. 1: Diutarónómì 22:1-19
No. 2: Bí A Ṣe Lè Mú Inú Ọlọ́run Dùn (lr orí 40)
No. 3: Amágẹ́dọ́nì Logun Tí Ọlọ́run Máa Lò Láti Fòpin sí Ìwà Burúkú (td 4A)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 11
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Ojúṣe Wa Bá A Ṣe Ń Pín Àwọn Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 133, ìpínrọ̀ 1 sí 3. Sọ ojúṣe tí akéde kọ̀ọ̀kan ní láti máa lo àwọn ìwé wa lọ́nà tó dáa.
20 min: “Ìgbà Wo Ló Yẹ Ká Pa Dà Lọ Sọ́dọ̀ Àwọn Tó Fetí sí Ọ̀rọ̀ Wa?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ní kí akéde kan ṣàṣefihàn bó ṣe pa dà lọ sọ́dọ̀ ẹnì kan tó sì ti múra sílẹ̀ láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú onítọ̀hún.
Orin 214