Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ December 14
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ DECEMBER 14
Orin 41
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jóṣúà 6-8
No. 1: Jóṣúà 8:1-17
No. 2: Omi Pa Ayé Kan Run—Ǹjẹ́ Irú Ẹ̀ Tún Lè Ṣẹlẹ̀ Mọ́? (lr orí 46)
No. 3: Kí Nìdí Tí Ìmọ̀ràn Inú Oníwàásù 7:21, 22 Fi Wúlò?
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 161
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
15 min: Kí Nìdí Táyà Mi Fi Máa Ń Já Láti Sọ Ohun Tí Mo Gbà Gbọ́ Fáwọn Ẹlòmíì? Àsọyé tá a gbé ka Jí! July–September 2009, ojú ìwé 22 sí 25. Ṣe àṣefihàn bí àwọn òbí kan ṣe ń kọ́ ọmọ wọn bó ṣe máa dáhùn àwọn ìbéèrè tí wọ́n bá bi í níléèwé, nígbà Ìjọsìn Ìdílé. Kí wọ́n mú ọ̀kan lára àwọn ìbéèrè tó wà lójú ìwé 23, kí wọ́n ṣèwádìí lórí rẹ̀, kí wọ́n jíròrò rẹ̀, kí wọ́n wá fi bí ọmọ náà ṣe máa dáhùn ìbéèrè náà dánra wò.
15 min: “Wàásù Pẹ̀lú Ìjẹ́kánjúkánjú!” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 4, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tó nítara, kó o bi í láwọn ìbéèrè yìí: Kí làwọn ohun tó o ti ṣe tí àwọn ohun tí kò pọn dandan nínú ayé kò fi dẹrù pa ọ́? Àwọn ọ̀nà wo lo ti gbà jàǹfààní nínú wíwàásù pẹ̀lú ìjẹ́kánjúkánjú?
Orin 92