Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ December 21
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ DECEMBER 21
Orin 73
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
lv orí 14 ìpínrọ̀ 10 sí 14, àpótí tó wà lójú ìwé 164 sí 165, àfikún tó wà lójú ìwé 222 sí 223
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jóṣúà 9-11
No. 1: Jóṣúà 9:1-15
No. 2: Bí A Ṣe Lè Mọ̀ Pé Amágẹ́dọ́nì Ti Sún Mọ́lé (lr orí 47)
No. 3: Ayé Tuntun Ọlọ́run, Ayé Àlàáfíà—Ìwọ Lè Wà Níbẹ̀ (lr orí 48)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 4
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
15 min: Múra Sílẹ̀ Láti Lo Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Ṣe àṣefihàn kan tó dá lórí bí alábòójútó àwùjọ kan ṣe ń sọ bó ṣe máa lo ìwé ìròyìn lóde ẹ̀rí fún àkéde kan tó jẹ́ ọ̀dọ́, kí ó sọ ìdí tó fi yan ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ yẹn, ìbéèrè tó máa bi onílé àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó fẹ́ kà. Akéde náà sọ pé òun ní ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kan lọ́kàn, àmọ́ òun fẹ́ kí alábòójútó àwùjọ náà bá òun ṣàtúnṣe díẹ̀ sí i. Wọ́n wá yan ìbéèrè kan tó bá àpilẹ̀kọ tí akéde náà fẹ́ lò mu, wọ́n sì yan ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó máa lò.
15 min: “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àkànṣe ti Ọdún 2010.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
Orin 93