Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní June: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Bí onílé bá ti ní ìwé yìí, ẹ lè fún un ní ìwé èyíkéyìí tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ tí ìjọ bá ní lọ́wọ́. July àti August: Ẹ lè lo èyíkéyìí lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 tó bá wà lọ́wọ́: Ẹmi Awọn Oku, Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!, Ki Ni Ète Igbesi-Aye—Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? àti Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I? Ẹ tún lè lo àwọn ìwé pẹlẹbẹ míì tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ tí ìjọ bá ní lọ́wọ́. September: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tẹ́ ẹ bá fún àwọn èèyàn ní ìwé náà.
◼ Ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tá a máa ṣe bẹ̀rẹ̀ láti oṣù September, a máa jíròrò àwọn fídíò wa tó dá lórí bí Bíbélì ṣe ń nípa lórí ìgbésí ayé àwa èèyàn àti bí àwọn ìtàn àti àsọtẹ́lẹ̀ inú rẹ̀ ṣe péye tó, ìyẹn The Bible—Its Power in Your Life àti The Bible—Accurate History, Reliable Prophecy. Bí ẹ bá máa nílò àwo DVD tí àwọn fídíò yìí wà lórí rẹ̀, ìyẹn The Bible—A Book of Fact and Prophecy, a rọ̀ yín pé kí ẹ kọ̀wé béèrè fún un nípasẹ̀ ìjọ yín kó tó pẹ́ jù.