“A Fi Ọgbọ́n Hàn Ní Olódodo Nípasẹ̀ Àwọn Iṣẹ́ Rẹ̀”
1. Irú ojú wo ni àwọn kan fi ń wò wá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
1 Nígbà míì àwọn èèyàn lè má fetí sí ìwàásù wa bóyá tórí wọ́n ṣì wá lóye tàbí torí wọ́n ti sọ ọ̀rọ̀ tí kì í ṣe òótọ́ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún wọn. Ó lè jẹ́ ọ̀rọ̀ tí kì í ṣe òótọ́ tí àwọn oníròyìn gbé jáde ló jẹ́ kí wọ́n máa fi ojú tí kò dáa wò wá. Ní àwọn àgbègbè kan, wọ́n tiẹ̀ ń pè wá ní “ẹ̀sìn eléwu.” Kí ló yẹ ká ṣe táwọn èèyàn bá ń ṣàríwísí wa?
2. Kí ni kò ní jẹ́ ká rẹ̀wẹ̀sì táwọn èèyàn bá ń ṣàríwísí wa?
2 Máa Ní Èrò Tó Dára: Ní ọ̀rúndún kìíní, ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn èèyàn ní èrò tí kò tọ́ nípa Jésù àti àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà míì, wọ́n sì sọ̀rọ̀ òdì sí wọn. (Ìṣe 28:22) Síbẹ̀, wọn kò jẹ́ kí àríwísí táwọn èèyàn ṣe yìí mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í tijú lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Jésù sọ pé: “A fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.” (Mát. 11:18, 19) Jésù ń fìtara bá a lọ láti ṣe ohun tí Baba rẹ̀ fẹ́, ó dá a lójú pé àwọn tó dìídì fẹ́ mọ òtítọ́ máa mọyì ìhìn rere. Bá a bá ń fi sọ́kàn pé wọ́n ṣe àìdáa sí Ọmọ Ọlọ́run pàápàá, èyí kò ní jẹ́ ká rẹ̀wẹ̀sì.
3. Kí nìdí tí kò fi yẹ kó yà wá lẹ́nu pé àwọn kan ń sọ̀rọ̀ wa láìdáa, wọ́n sì ń ta kò wá?
3 Jésù sọ pé ayé máa kórìíra àwọn ọmọlẹ́yìn òun bí wọ́n ṣe kórìíra òun. (Jòh. 15:18-20) Torí náà, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu bí àwọn èèyàn bá ń sọ ohun tí kò dáa nípa wa tí wọ́n sì ń ta kò wá. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, bá a ṣe túbọ̀ ń sún mọ́ òpin àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, tí ìbínú Sátánì sì túbọ̀ ń ru, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé ńṣe làwọn èèyàn á túbọ̀ máa ṣàríwísí wa. (Ìṣí. 12:12) Ó yẹ kí èyí mú inú wa dùn gan-an ni, torí ó fi hàn pé òpin ò ní pẹ́ dé bá ayé tí Sátánì ń darí yìí.
4. Báwọn èèyàn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù wa, kí ló yẹ ká ṣe?
4 Máa Fèsì Tìfẹ́tìfẹ́: Bí wọ́n bá sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí wa, ó yẹ ká fèsì lọ́nà tó máa fi ìfẹ́ àti inúure hàn. (Òwe 15:1; Kól. 4:5, 6) Bó bá ṣeé ṣe, a lè ṣàlàyé fún ẹni tá à ń wàásù fún pé, ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ tí kì í ṣe òótọ́ ni àwọn èèyàn máa ń sọ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí ká béèrè ìdí tí kò fi fẹ́ fetí sọ́rọ̀ wa. Bá a bá fi inúure fèsì, èyí lè mú kí ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọminú sí ohun tó ti gbọ́ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ́lẹ̀, kí ó sì fetí sílẹ̀ nígbà tá a bá tún kàn sí i. Àmọ́ ṣá o, bí ẹni tá à ń wàásù fún bá ń bínú gan-an, ohun tó máa dáa jù ni pé ká rọra fi ibẹ̀ sílẹ̀. Ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé, ohun yòówù káwọn èèyàn máa sọ tàbí kí wọ́n máa rò nípa wa, Jèhófà mọyì iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.—Aísá. 52:7.