Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ August 2
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ AUGUST 2
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Àwọn Ọba 18-20
No. 1: 1 Àwọn Ọba 18:21-29
No. 2: Kí Ló Túmọ̀ Sí Pé Ọ̀run àti Ayé Yóò Kọjá Lọ? (Ìṣí. 21:1)
No. 3: Àwọn Wo Ló Ń Lọ sí Ọ̀run? (td 41A)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Àwọn Ọ̀nà Tó O Lè Gbà Mú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Gbòòrò Sí I—Apá Kẹrin. Àsọyé tá a gbé ka ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 116, ìpínrọ̀ 1, sí ìpínrọ̀ 4. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tàbí méjì tí wọ́n ṣèrànwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Ní kí wọ́n sọ ohun tí wọ́n ti gbádùn nínú àǹfààní iṣẹ́ ìsìn náà.
10 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Àwọn Ìrírí Tá A Ní Nígbà Tá A Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Sọ àwọn àṣeyọrí tẹ́ ẹ ti ṣe láwọn ọjọ́ tẹ́ ẹ yàn láti máa fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ àwọn èèyàn lákànṣe. Ní káwọn ará sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ní. Ẹ lè ṣe àṣefihàn ìrírí kan tàbí méjì tó ta yọ. Ní ìparí iṣẹ́ rẹ, ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tá a bá ẹnì kan sọ̀rọ̀.