Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ October 11
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ OCTOBER 11
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cf ori 11 ìpínrọ̀ 15 sí 21 àti àpótí tó wà lójú ìwé 117
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Kíróníkà 5-7
No. 1: 1 Kíróníkà 6:31-47
No. 2: Ṣé Gbogbo Ìsìn Ló Dára? (td 5B)
No. 3: Báwo Lèèyàn Aláìpé Ṣe Lè Jẹ́ Mímọ́? (1 Pét. 1:16)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Báwo Ló Ṣe Yẹ Kó O Fèsì? Ìjíròrò tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 69, ìpínrọ̀ 1 sí 5. Ṣe àṣefihàn bí aṣáájú-ọ̀nà kan ṣe dá ẹni tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lóhùn nígbà tí akẹ́kọ̀ọ́ náà fẹ́ ṣe ìpinnu ara ẹni. Kí akẹ́kọ̀ọ́ náà béèrè lọ́wọ́ aṣáájú-ọ̀nà pé, “Kí lo máa ṣe tó bá jẹ́ pé ìwọ lo wà nírú ipò tí mo wà yìí?”
10 min: Wíwà Ní Mímọ́ Nípa Tara Ń Fògo fún Ọlọ́run. Àsọyé tá a gbé ka ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 137, ìpínrọ̀ 2, sí ojú ìwé 138, ìpínrọ̀ 3. Ní kí àwọn ará sọ bí ìrísí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó mọ́ tónítóní tó sì wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì ṣe fà wọ́n mọ́ra tó sì mú kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.
10 min: “Má Fòyà.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.