Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ October 18
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ OCTOBER 18
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Kíróníkà 8-11
No. 1: 1 Kíróníkà 11:1-14
No. 2: Báwo Ni Ẹ̀mí àti Ìyàwó Ṣe Ń Sọ Pé “Máa Bọ̀”? (Ìṣí. 22:17)
No. 3: Ó Yẹ Káwọn Kristẹni Máa Lo Orúkọ Ọlọ́run (td 34A)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Pé Ká Máa Wo Ojú Ẹni Tá À Ń Wàásù Fún. Ìjíròrò tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 124, ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 125, ìpínrọ̀ 4.
20 min: “A Máa Lo Ìwé Pẹlẹbẹ Tuntun Lóde Ẹ̀rí!” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 1, sọ ohun tó wà nínú ìwé pẹlẹbẹ náà ní ṣókí. Lẹ́yìn ìjíròrò ìpínrọ̀ 2 àti 3, ṣe àṣefihàn àwọn àbá tó wà níbẹ̀. Lẹ́yìn ìjíròrò ìpínrọ̀ 4, ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà ìpadàbẹ̀wò.