Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ October 25
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ OCTOBER 25
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Kíróníkà 12-15
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
8 min: Àwọn ìfilọ̀. “Bó O Bá Nílò Ìtẹ̀jáde Ti Èdè Ilẹ̀ Òkèèrè Ní Kíákíá.” Àsọyé.
12 min: Bá A Ṣe Wà Níṣọ̀kan Kárí Ayé Ń Fi Ìyìn fún Jèhófà. Àsọyé tá a gbé ka ìwéA Ṣètò Wa, ojú ìwé 165, ìpínrọ̀ 2, sí ìsọ̀rí tó wà lójú ìwé 168. Ní kí àwọn ará sọ àwọn ìrírí mélòó kan tí ètò Ọlọ́run ti tẹ̀ jáde, tó fi hàn bí ìṣọ̀kan àti ìfẹ́ tó wà láàárín wa ṣe jẹ́rìí fáwọn èèyàn.
15 min: Ó Yẹ Ká Ní Ẹ̀mí Ìfara-Ẹni-Rúbọ. (Lúùkù 9:23) Ìjíròrò tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ September 15, 2000, ojú ìwé 21 sí 24. Sọ àwọn ìrírí tí ètò Ọlọ́run tẹ̀ jáde tó sì bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu tàbí èyí tó ṣẹlẹ̀ ládùúgbò yín, tó fi bí àwọn ará wa ṣe fi ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ hàn lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ní kí àwọn ará sọ àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́ látinú àwọn ìrírí náà.