ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/10 ojú ìwé 3
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
km 10/10 ojú ìwé 3

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣàtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní October 25, 2010. Àtúnyẹ̀wò yìí dá lórí àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe láàárín ọ̀sẹ̀ September 6 sí October 25, 2010, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ á sì darí rẹ̀ fún ogún [20] ìṣẹ́jú.

1. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú bí Jèhóáṣì kò ṣe ta ọfà sílẹ̀ ju ẹ̀ẹ̀mẹta péré lọ? (2 Ọba 13:14-19) [w05 8/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 11]

2. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ tá a bá ronú lórí ìgbésí ayé Asaráyà (ìyẹn Ùsáyà Ọba)? (2 Ọba 15:1-6) [w91 7/15 ojú ìwé 29 sí 30]

3. Ṣé lóòótọ́ ni Hesekáyà wá ìrànlọ́wọ́ lọ sí Íjíbítì? (2 Ọba 18:19-21, 25) [w05 8/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 5]

4. Kí nìdí tá a fi sọ̀rọ̀ Jèhófà bí ẹni tó ń “ṣẹ̀dá” ète rẹ̀? (2 Ọba 19:25) [w99 8/15 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 3]

5. Ìdánilójú wo ni ìwé 2 Àwọn Ọba 24:3, 4 fún wa? [w05 8/1 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 2]

6. Kí nìdí tí 1 Sámúẹ́lì 16:10, 11 fi pe Dáfídì ní ọmọkùnrin kẹjọ tí Jésè bí nígbà tí Ẹ́sírà pè é ní ọmọkùnrin keje? (1 Kíró. 2:15) [w02 9/15 ojú ìwé 30 sí 31]

7. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn ará Gílíádì ìgbàanì? (1 Kíró. 5:10, 18-22) [w05 10/1 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 7]

8. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ lára àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ aṣọ́bodè? (1 Kíró. 9:26, 27) [w05 10/1 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 8]

9. Báwo ni orin kíkọ ti ṣe pàtàkì tó ní Ísírẹ́lì àtijọ́? (1 Kíró. 9:33) [w94 5/1 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 8 àti ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 13]

10. Kí ló burú nínú ohun tí Dáfídì ṣe gẹ́gẹ́ bó ṣe wà ní 1 Kíróníkà 13:11? [w05 10/1 ojú ìwé 11, ìpínrọ̀ 2]

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́