Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ November 22
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ NOVEMBER 22
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cf orí 13 ìpínrọ̀ 18 sí 21 àti àpótí tó wà lójú ìwé 138
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 2 Kíróníkà 1-5
No. 1: 2 Kíróníkà 3:1-13
No. 2: Kí Ẹ̀sìn Kristẹni Tó Dé, Orí Kí Ni Jèhófà Gbé Ìdáríjì Ẹ̀ṣẹ̀ Kà? (Róòmù 3:24, 25)
No. 3: Ṣé Ẹ̀sìn Tuntun Ni Ẹ̀sìn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? (td 12A)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: “Ìpèsè Tẹ̀mí fún Àwọn Kristẹni Òjíṣẹ́.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Bí ẹ bá ti mọ ọjọ́ tẹ́ ẹ máa ṣe àpéjọ àyíká yín, kó o sọ ọ́ fún àwọn ará. Ní kí àwọn ará sọ àwọn àǹfààní tí wọ́n ti jẹ ní àwọn àpéjọ àyíká tẹ́ ẹ ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí.
20 min: “Báwo Lo Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ fún Ọkọ Tàbí Aya Tó Jẹ́ Aláìgbàgbọ́?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ọkọ tàbí aya kan tó ti fìgbà kan rí jẹ́ aláìgbàgbọ́. Ní kó sọ bí àwọn ará ṣe ràn án lọ́wọ́ tí èyí sì mú kó nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ òtítọ́.