Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ December 20
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ DECEMBER 20
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 2 Kíróníkà 20-24
No. 1: 2 Kíróníkà 20:1-12
No. 2: Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Kọ́ Èdè Mímọ́ Gaara Ká sì Máa Sọ Ọ́? (Sef. 3:9)
No. 3: Àwọn Ìbùkún Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Mú Wá (td-YR 21A)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
15 min: Ǹjẹ́ O Ti Lo Àwọn Àbá Wọ̀nyí? Ìjíròrò. Ní ṣókí, sọ̀rọ̀ lórí àwọn àpilẹ̀kọ yìí tó jáde nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa lẹ́nu àìpẹ́ yìí: “Ǹjẹ́ O Ti Fi Bá A Ṣe Ń Ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Han Àwọn Èèyàn Nígbà Àkọ́kọ́?” àti “Bá A Ṣe Lè Kọ́ Àwọn Ẹni Tuntun Láti Máa Wàásù (km 5/10) àti “O Lè Jẹ́rìí Láìjẹ́-bí-Àṣà!” (km 8/10). Ni kí àwọn ará sọ̀rọ̀ lórí bí wọ́n ṣe lo àwọn àbá tó wà nínú àwọn àpilẹ̀kọ yìí àti bó ti ṣe ṣe wọ́n láǹfààní.
15 min: “Àwọn Àpilẹ̀kọ Tuntun Tá A Lè Fi Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Kó o tó bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò náà, fún àwọn akéde tí kò bá mú Ilé Ìṣọ́ January 1, 2011 wá ní ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan. Ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ, ṣe àṣefihàn kan tàbí méjì nípa bá a ṣe lè fi àpilẹ̀kọ náà, Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run—Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.