Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ November 14
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ NOVEMBER 14
Orin 49 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 12 ìpínrọ̀ 14 sí 20 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Oníwàásù 1-6 (10 min.)
No. 1: Oníwàásù 6:1-12 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ṣé Sísọ̀rọ̀ Ní Ahọ́n Àjèjì Jẹ́ Ẹ̀rí Tó Dájú Pé Ẹnì Kan Rí Ojú Rere Ọlọ́run?—td 32E (5 min.)
No. 3: Ìdí Tí Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Fi Ń Pa Àṣẹ Tó Wà Nínú Róòmù 12:19 Mọ́ (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀.
10 min: Ǹjẹ́ O Máa Ń Rí Ayọ̀ Nínú “Àǹfààní Ìfúnni Onínúrere”? Alàgbà ni kó sọ àsọyé yìí, a gbé e ka Ilé Ìṣọ́ November 15, 2011, ojú ìwé 22 sí 23.
10 min: “A Gbọ́dọ̀ Bomi Rin Irúgbìn Kí Ó Lè Dàgbà.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti jíròrò ìpínrọ̀ 3, ṣe àṣefihàn akéde kan tó ń dá sọ̀rọ̀ bó ṣe ń múra ìpadàbẹ̀wò sílẹ̀. Ó ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ tó ṣe nípa ẹni tó fẹ́ lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì ronú nípa bó ṣe máa dáhùn ìbéèrè tó sọ fún onílé pé òun máa dáhùn nígbà tí òun bá pa dà wá àti bó ṣe máa bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìwé Kí Ní Bíbélì Fi Kọ́ni kọ́ ẹni náà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní ṣókí, ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ìgbà téèyàn lè ròyìn ìpadàbẹ̀wò nínú ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 85, ìpínrọ̀ 3.
10 min: “Kí Orúkọ Ọlọ́run Di Sísọ Di Mímọ́.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Sọ ọjọ́ tẹ́ ẹ máa lọ sí àpéjọ àyíká, tẹ́ ẹ bá ti mọ̀ ọ́n.
Orin 98 àti Àdúrà