Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ May 13
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MAY 13
Orin 4 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 9 ìpínrọ̀ 8 sí 13 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jòhánù 5-7 (10 min.)
No. 1: Jòhánù 6:22-40 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ọlọ́run Kọ́ Ló Ń Fa Wàhálà Tó Wà Nínú Ayé—td 31A (5 min.)
No. 3: Báwo La Ṣe Lè Fi Ìlànà Tó Wà Nínú Númérì 15:37-40 Sílò? (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Ìwé Tá A Máa Lò Lóṣù May àti June. Àsọyé. Ṣàlàyé ṣókí nípa ìdí tí àwọn èèyàn fi máa nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú tẹ́ ẹ fẹ́ lò ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Ṣe àṣefihàn kan tàbí méjì tó dá lórí bẹ́ ẹ ṣe lè lo ìwé àṣàrò kúkúrú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé.
10 min: Kí La Rí Kọ́? Ìjíròrò. Ẹ ka Mátíù 5:11, 12 àti Mátíù 11:16-19. Ẹ jíròrò bí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
10 min: “Kí Ló Ń Mú Ká Máa Wàásù?” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
Orin 91 àti Àdúrà