Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 10
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JUNE 10
Orin 114 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 10 ìpínrọ̀ 14 sí 19 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ìṣe 1-4 (10 min.)
No. 1: Ìṣe 1:15–2:4 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Gbogbo Kristẹni Ló Gbọ́dọ̀ Wàásù Ìhìn Rere—td 20A (5 min.)
No. 3: Báwo Ni Ọ̀nà Táwọn Èèyàn Ayé Ń Gbà Ronú Ṣe Dà Bí Afẹ́fẹ́ Tó Lè Ṣekú Pani?—Éfé. 2:1, 2 (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Pé Ká Máa Wo Ojú Ẹni Tá À Ń Bá Sọ̀rọ̀. Àsọyé tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 124, ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 125, ìpínrọ̀ 4. Ní ṣókí, ṣe àṣefihàn bí akéde kan ṣe ń wàásù láìwo ojú ẹni tó ń bá sọ̀rọ̀. Lẹ́yìn náà, kí akéde náà tún àṣefihàn náà ṣe, kó sì wo ojú ẹni tó ń bá sọ̀rọ̀.
10 min: Àwọn Àṣeyọrí Wo La Ṣe? Ìjíròrò. Akọ̀wé ni kó ṣe iṣẹ́ yìí. Sọ àwọn àṣeyọrí tẹ́ ẹ ṣe lásìkò Ìrántí Ikú Kristi, kó o sì gbóríyìn fún ìjọ fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣe. Ní kí àwọn ará sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n ń pín ìwé ìkésíni sí Ìrántí Ikú Kristi tàbí nígbà tí wọ́n ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.
10 min: “Ǹjẹ́ O Máa Ń Múra Tán Láti Ṣe Ìyípadà?” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
Orin 74 àti Àdúrà