Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 8
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JULY 8
Orin 43 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 11 ìpínrọ̀ 15 sí 21 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ìṣe 15-17 (10 min.)
No. 1: Ìṣe 16:16-34 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Kí Nìdí Táwa Kristẹni Fi Ń Láyọ̀ Tí Wọ́n Bá Ṣe Inúnibíni sí Wa?—Mát. 5:11, 12 (5 min.)
No. 3: Ìdí Tí Inú Ọlọ́run Kò Fi Dùn sí Jíjọ́sìn Àwọn Baba Ńlá—td 22A (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Ọ̀nà Tá A Gbà Ń Wàásù Ìhìn Rere—Bó O Ṣe Lè Máa Pe Àwọn Olùfìfẹ́hàn Wá Sínú Ètò Jèhófà. Àsọyé tá a gbé ka ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 99, ìpínrọ̀ 2 sí 4. Ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ṣe lo ìwé Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní? láti darí àwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sínú ètò Ọlọ́run.
10 min: Dán Jèhófà Wò, Kí O sì Gba Ìbùkún Títí Kì Yóò Fi Sí Àìní Mọ́. (Mál. 3:10) Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu aṣáájú-ọ̀nà déédéé méjì tàbí mẹ́ta. Kí ni wọ́n ń gbádùn jù nínú iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà? Báwo ni iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ṣe jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà? Ní kí wọ́n sọ ìrírí kan tó ń gbéni ró tí wọ́n ní. Gba àwọn akéde yòókù níyànjú láti ronú lórí bí àwọn náà ṣe lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní oṣù September.
10 min: “Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Wòlíì—Jóẹ́lì.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
Orin 54 àti Àdúrà