Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 5
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ AUGUST 5
Orin 77 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 12 ìpínrọ̀ 20 sí 25 àti àpótí tó wà lójú ìwé 151 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Róòmù 1-4 (10 min.)
No. 1: Róòmù 3:21–4:8 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ìdí Táwa Kristẹni Fi Ka Ara Wa sí “Àtìpó àti Olùgbé fún Ìgbà Díẹ̀.”—1 Pét. 2:11; 1 Jòh. 2:15-17 (5 min.)
No. 3: Ìdí Tó Fi Pọn Dandan Pé Kí Kristẹni Ṣe Batisí—td 17A (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Àbá Tá A Lè Lò Láti Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Lóṣù August. Ìjíròrò. Fi ààbọ̀ ìṣẹ́jú sí ìṣẹ́jú kan sọ ìdí táwọn èèyàn fi máa nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ìwé ìròyìn náà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Lẹ́yìn náà, lo àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Ilé Ìṣọ́ August, ní kí àwọn ará sọ àwọn ìbéèrè tó lè mú kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wọn. Lẹ́yìn náà, kí wọ́n sọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn. Ohun kan náà ni kó o ṣe nípa àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Jí! July–August 2013. Tí àkókò bá ṣì wà, ẹ tún lè jíròrò àpilẹ̀kọ mìíràn nínú ìwé ìròyìn méjèèjì. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà lọni.
10 min: Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Ǹjẹ́ O Ti Múra Sílẹ̀ Fún Sáà Tuntun Tó Fẹ́ Bẹ̀rẹ̀ Nílé Ẹ̀kọ́? Ìjíròrò. Ní kí àwọn ará sọ díẹ̀ lára ìṣòro tí àwọn ọ̀dọ́ wa sábà máa ń ní níléèwé. Ṣàlàyé bí àwọn òbí ṣe lè lo ìwé atọ́ka àwọn ìtẹ̀jáde, ìyẹn Index, ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé, Ìkànnì wa àtàwọn ìtẹ̀jáde míì tí ètò Ọlọ́run ṣe nígbà ìjọsìn ìdílé wọn láti múra àwọn ọmọ wọn sílẹ̀ de onírúurú ìṣòro tí wọ́n lè bá pàdé níléèwé. (1 Pét. 3:15) Yan kókó ọ̀rọ̀ kan tàbí méjì, kó o sì sọ díẹ̀ lára ohun tí àwọn ìtẹ̀jáde náà sọ tó lè ṣèrànwọ́. Ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ṣe wàásù níléèwé.
Orin 41 àti Àdúrà