Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ August 19
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ AUGUST 19
Orin 51 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 13 ìpínrọ̀ 8 sí 13 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Róòmù 9-12 (10 min.)
No. 1: Róòmù 9:19-33 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Bíbélì Ní Ìmísí Ọlọ́run—td 8A (5 min.)
No. 3: Ìdí Tí Bíbélì Fi Sọ Pé A Kò Gbọ́dọ̀ Bẹ̀rù Èèyàn—Lúùkù 12:4-12 (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: “Àwọn Àbá Tá A Lè Lò Láti Fi Ìwé Ìròyìn Lọni.” Ìjíròrò.
15 min: “Ẹ Jẹ́ Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà Pẹ̀lú Gbogbo Ènìyàn.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ní ṣókí, ṣe àṣefihàn alápá méjì tó máa jẹ́ ká mọ ohun tó yẹ ká ṣe àti ohun tí kò yẹ ká ṣe tí onílé bá bínú sí wa. Ẹ kọ́kọ́ ṣe àṣefihàn ohun tí kò yẹ ká ṣe, lẹ́yìn náà, kẹ́ ẹ wá ṣe àṣefihàn ohun tá a lè ṣe.
10 min: Máa Fi Àìṣojo Wàásù. (Ìṣe 4:29) Ìjíròrò tó dá lórí Ìwé Ọdọọdún 2013, ojú ìwé 49, ìpínrọ̀ 1 sí 6 àti ojú ìwé 69, ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 70, ìpínrọ̀ 2. Ní kí àwọn ará sọ ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́.
Orin 92 àti Àdúrà