Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ August 26
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ AUGUST 26
Orin 63 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 13 ìpínrọ̀ 14 sí 19 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Róòmù 13-16 (10 min.)
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run (20 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: “Ẹ Máa Fi Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọni ní Sátidé Àkọ́kọ́.” Àsọyé. Lẹ́yìn náà, ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Sátidé àkọ́kọ́ lóṣù September. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n wá sóde ẹ̀rí lọ́jọ́ yẹn.
10 min: Àwọn Ọ̀nà Tá A Gbà Ń Wàásù Ìhìn Rere—Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Ara Ẹni àti ti Àwùjọ. Ìjíròrò tó dá lórí ìwé A Sètò Wa, ojú ìwé 102, ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 104, ìpínrọ̀ 1. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ìránṣẹ́ tó ń bójú tó ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ yín. Ní kó sọ ètò tó wà nílẹ̀ fún gbígba ìpínlẹ̀ ìwàásù àti bẹ́ ẹ ṣe ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀.
10 min: Irú Èèyàn Wo Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Ìjíròrò tó dá lórí Ẹ̀kọ́ 1 nínú ìwé Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní? Ṣe àṣefihàn kan tó dá lórí bí akéde kan ṣe ń ṣàlàyé irú ẹni tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ fún ẹni tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Orin 116 àti Àdúrà