Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní August: Ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! tàbí èyíkéyìí lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé méjìlélọ́gbọ̀n yìí: Tẹ́tí sí Ọlọ́run tàbí Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé tàbí Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I? Tẹ́ ẹ bá pàdé ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí, ẹ fún un ní ìwé Ìgbàgbọ́ Òdodo Ló Máa Mú Kó O Ní Ayọ̀ tàbí Ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run Ló Máa Ṣamọ̀nà Ẹ̀dá Wọ Párádísè. September àti October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! November: Ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́? tàbí ìwé àṣàrò kúkúrú èyíkéyìí tí ìjọ bá ní lọ́wọ́.
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀sẹ̀ October 28, 2013, ìwé Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní? la máa bẹ̀rẹ̀ sí í kà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ. Lẹ́yìn ìyẹn, a ó ka ìwé Sún Mọ́ Jèhófà bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀sẹ̀ January 6, 2014. Kí àwọn ìjọ tí kò bá ní àwọn ìwé yìí lọ́wọ́ jọ̀wọ́ béèrè fún un tí wọ́n bá ń kọ̀wé béèrè fún àwọn ìwé tí wọ́n nílò.
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù September, àkòrí àsọyé fún gbogbo ènìyàn tí àwọn alábòójútó àyíká yóò máa sọ ni, “Bá A Ṣe Lè Fi Ìfẹ́ àti Ìgbàgbọ́ Ṣẹ́gun Ayé.”