Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ September 2
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ SEPTEMBER 2
Orin 47 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 13 ìpínrọ̀ 20 sí 26 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Kọ́ríńtì 1-9 (10 min.)
No. 1: 1 Kọ́ríńtì 4:18–5:13 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Bíbélì Wúlò Fún Wa Lóde Òní—td 8B (5 min.)
No. 3: Bí Àwa Kristẹni Ṣe Lè Láyọ̀ Bá A Bá Tiẹ̀ Jẹ́ Aláìlera—Fílí. 4:6, 7 (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Àbá Tá A Lè Lò Láti Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Lóṣù September. Ìjíròrò. Fi ààbọ̀ ìṣẹ́jú sí ìṣẹ́jú kan sọ ìdí táwọn èèyàn fi máa nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ìwé ìròyìn náà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Lẹ́yìn náà, lo àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Ilé Ìṣọ́ September, ní kí àwọn ará sọ àwọn ìbéèrè tó lè mú kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wọn. Lẹ́yìn náà, kí wọ́n sọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn. Ohun kan náà ni kó o ṣe nípa àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Jí! September–October. Tí àkókò bá ṣì wà, ẹ tún lè jíròrò àpilẹ̀kọ mìíràn nínú ìwé ìròyìn méjèèjì. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà lọni.
10 min: Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Bánábà. Ìjíròrò. Ní kí àwọn ará sọ bí àpẹẹrẹ Bánábà ṣe lè fún wa níṣìírí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.
Orin 65 àti Àdúrà