Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ February 3
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ FEBRUARY 3
Orin 22 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 2 ìpínrọ̀ 12 sí 20 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 21-24 (10 min.)
No. 1: Jẹ́nẹ́sísì 23:1-20 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Báwo Ni Ìwòsàn Tẹ̀mí Ṣe Ṣe Pàtàkì Tó?—td 32A (5 min.)
No. 3: “Èyí Ni Ọmọ Mi”—lr orí 5 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Fi Àwọn Ìwé Ìròyìn Lọni Lóṣù February. Ìjíròrò. Kọ́kọ́ fi àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó wà lójú ìwé yìí ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè fi àwọn ìwé ìròyìn náà lọni. Lẹ́yìn náà, ẹ jíròrò àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ náà láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin, nípa kíka gbólóhùn kan tàbí méjì, kó o wá ní kí àwọn ará sọ ohun tó túmọ̀ sí. Rán wọn létí pé kí wọ́n sọ ọ́ ní ọ̀rọ̀ tara wọn, wọ́n sì lè yí àwọn àbá náà pa dà tàbí kí wọ́n gbé ọ̀rọ̀ wọn kalẹ̀ lọ́nà míì. Ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ, fún gbogbo àwọn ará níṣìírí pé kí wọ́n ka àwọn ìwé ìròyìn náà dáadáa, kí wọ́n sì fìtara kópa nínú fífi àwọn ìwé ìròyìn náà lọni.
10 min: Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Nípa Àwọn Èso Wọn Ni Ẹ Ó Fi Dá Wọn Mọ̀. (Mát. 7:16) Ìjíròrò tá a gbé ka Ìwé Ọdọọdún ti 2013, ojú ìwé 47, ìpínrọ̀ 1 àti 2; àti ojú ìwé 52, ìpínrọ̀ 1 sí 6. Ní kí àwọn ará sọ ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́.
Orin 25 àti Àdúrà