Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ June 9
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JUNE 9
Orin 24 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 8 ìpínrọ̀ 9 sí 16 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Léfítíkù 1-5 (10 min.)
No. 1: Léfítíkù 4:16-31 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Máa Fọ́nnu?—lr orí 21 (5 min.)
No. 3: Àwọn Ànímọ́ Ọlọ́run—td 34D (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
15 min: Ǹjẹ́ O Ti Gbìyànjú Ẹ̀ Wò? Ìjíròrò. Ní ṣókí, sọ àwọn àbá tó jáde nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ìyẹn àwọn àbá tó jáde nínú àpilẹ̀kọ wọ̀nyí: “Ọ̀nà Tuntun Tá A Fẹ́ Máa Gbà Wàásù Láwọn Ibi Tí Èrò Pọ̀ Sí” (km 7/13), “Bá A Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ Fáwọn Tá Ò Tíì Lè Fi Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́” (km 12/13), àti “Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Pẹ̀lú Àwọn Tó Ò Ń Fún Ní Ìwé Ìròyìn Déédéé” (km 1/14). Ní kí àwọn ará sọ àwọn àǹfààní tí wọ́n rí nígbà tí wọ́n lo àwọn àbá tó wà nínú àwọn àpilẹ̀kọ náà.
15 min: “A Fẹ́ Kí Oṣù August Jẹ́ Mánigbàgbé!” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó ṣe iṣẹ́ yìí. Fún àwọn ará ní ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan ìwé àṣàrò kúkúrú tuntun tá a pe àkòrí rẹ̀ ní, Ibo La Ti Lè Rí Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè Pàtàkì Nípa Ìgbésí Ayé? kó o sì jíròrò ohun tó wà nínú rẹ̀. Sọ ètò tí ìjọ ṣe kẹ́ ẹ lè kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù yín.
Orin 107 àti Àdúrà