Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ July 28
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JULY 28
Orin 58 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 10 ìpínrọ̀ 18 sí 21, àpótí tó wà lójú ìwé 106 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Númérì 1-3 (10 min.)
No. 1: Númérì 3:21-38 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ta Ni Ọlọ́run Rẹ?—lr orí 27 (5 min.)
No. 3: Àwọn Ìbùkún Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Mú Wá—td 21A (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ Fún Sáà Tuntun Tó Máa Bẹ̀rẹ̀ Nílé Ẹ̀kọ́? Ìjíròrò. Ní kí àwọn ará sọ díẹ̀ lára àwọn ìṣòro táwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni máa ń bá pàdé níléèwé. Ṣàlàyé bí àwọn òbí ṣe lè lo Ìkànnì wa àtàwọn ìwé míì tí ètò Ọlọ́run ṣe, láti múra àwọn ọmọ wọn sílẹ̀. (1 Pét. 3:15) Yan ìṣòro kan tàbí méjì táwọn ọ̀dọ́ sábà máa ń ní, kó o sì sọ díẹ̀ lára ohun tí àwọn ìtẹ̀jáde náà sọ tó lè wúlò fún wọn. Ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ṣe wàásù níléèwé.
10 min: Fọ̀rọ̀ Wá Ọ̀rọ̀ Wò Lẹ́nu Akọ̀wé Ìjọ. Kí ni ojúṣe yín gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé ìjọ? Báwo ní àwọn alábòójútó àwùjọ àtàwọn akéde ṣe lè ràn yín lọ́wọ́ láti kó ìròyìn iṣẹ́ ìsìn jọ lásìkò, kó sì pé pérépéré? Báwo ni ìròyìn iṣẹ́ ìsìn ìjọ tó pé pérépéré ṣe lè mú kí àwọn alàgbà, alábòójútó àyíká àti ẹ̀ka ọ́fíìsì fún wa ní ìṣírí tá a nílò?
10 min: “Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Wòlíì —Sefanáyà.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
Orin 70 àti Àdúrà