Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ August 18
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ AUGUST 18
Orin 78 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 11 ìpínrọ̀ 17 sí 22, àti àpótí tó wà lójú ìwé 116 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Númérì 10-13 (10 min.)
No. 1: Númérì 10:1-16 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ohun Tí “Òpin Ayé” Túmọ̀ Sí—td 39A (5 min.)
No. 3: Ìrànlọ́wọ́ Láti Borí Ìbẹ̀rù—lr orí 30 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: “Pe Àwọn Ènìyàn Náà Jọpọ̀.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
10 min: “Ìwé Ìkésíni Pàtàkì.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fún gbogbo àwọn tó wà nípàdé ní ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan ìwé ìkésíni náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò ohun tó wà níbẹ̀. Sọ ìgbà tí ìjọ yín máa bẹ̀rẹ̀ sí í pín ìwé ìkésíni yìí àti ètò tí ìjọ ṣe kẹ́ ẹ lè kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Ṣe àṣefihàn kan ní ṣókí.
10 min: “Ẹ Tọ́jú Ìwà Yín Kí Ó Dára Lọ́pọ̀lọpọ̀ Láàárín Àwọn Orílẹ̀-Èdè.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Tún jíròrò èyí tó kan ìjọ yín nínú “Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Nípa Àpéjọ Àgbègbè Ọdún 2014” àti lẹ́tà tá a kọ sí gbogbo ìjọ ní August 3, 2013, nípa bá a ṣe lè dènà jàǹbá láwọn ìpàdé wa.
Orin 125 àti Àdúrà