ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/14 ojú ìwé 7
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
km 8/14 ojú ìwé 7

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní August 25, 2014.

  1. Báwo ni Léfítíkù 18:3 ṣe lè mú ká yẹra fún níní èrò tí kò tọ́ nípa ohun tó dára àti ohun tó burú? (Éfé. 4:17-19) [July 7, w02 2/1 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 4]

  2. Ẹ̀kọ́ wo ni àṣẹ tó wà nínú Léfítíkù 19:2 kọ́ wa, kí sì nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ sapá ká lè ṣègbọràn sí ohun tó sọ? [July 7, w09 7/1 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 5]

  3. Ẹ̀kọ́ wo ni ìlànà tó wà nínú òfin ayé ìgbàanì nípa pípèéṣẹ́ kọ́ wa lóde òní? (Léf. 19:9, 10) [July 7, w06 6/15 ojú ìwé 22 sí 23 ìpínrọ̀ 13]

  4. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé òfin tó sọ pé “ojú fún ojú” kò fọwọ́ sí i pé ká máa gbẹ̀san? (Léf. 24:19, 20) [July 14, w09 9/1 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 3 sí 4]

  5. Lábẹ́ irú àwọn ipò wo ni kò ti yẹ kí ọmọ Ísírẹ́lì kan gba èlé lórí owó tó bá yá ẹlòmíì, àmọ́ ìgbà wo ni kò burú láti gba owó èlé? (Léf. 25:35-37) [July 21, w04 5/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 3]

  6. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá ni Bíbélì sábà máa ń tọ́ka sí, nígbà tó jẹ́ pé ẹ̀yà mẹ́tàlá ni wọ́n? (Núm. 1:49, 50) [July 28, w08 7/1 ojú ìwé 21]

  7. Númérì 8:25, 26 sọ nípa iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe tí àwọn ọmọ Léfì ń ṣe, ẹ̀kọ́ wo la kọ́ níbẹ̀ tó bá kan pé ká fi ìgbatẹnirò hàn sáwọn àgbàlagbà? [Aug. 11, w04 8/1 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 1]

  8. Lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì, kí nìdí tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí í ráhùn, ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la sì kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí? (Núm. 11:4-6) [Aug. 18, w95 3/1 ojú ìwé 15 sí 16 ìpínrọ̀ 10]

  9. Ẹ̀kọ́ wo la kọ́ nínú ohun tí Mósè ṣe nígbà tí Ẹ́lídádì àti Médádì ń ṣe bíi wòlíì? (Núm. 11:27-29) [Aug. 18, w04 8/1 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 4]

  10. Ìlànà pàtàkì wo ni àṣẹ tí Ọlọ́run pa pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì “ṣe ìṣẹ́tí fún ara wọn sétí apá gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ wọn” kọ́ wa? (Núm. 15:37-39) [Aug. 25, w04 8/1 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 7]

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́