Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ September 1
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ SEPTEMBER 1
Orin 46 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 12 ìpínrọ̀ 9 sí 15 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Númérì 17-21 (10 min.)
No. 1: Númérì 17:1-13 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ibi Tí A Ti Lè Rí Ìtùnú Gbà—lr orí 31 (5 min.)
No. 3: Wà Lójúfò Nípa Tẹ̀mí Kó O Lè Dá Àmì Ọjọ́ Ìkẹyìn Mọ̀—td 39B (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Fi Àwọn Ìwé Ìròyìn Lọni Lóṣù September. Ìjíròrò. Kọ́kọ́ lo àwọn àbá méjì tó wà lójú ìwé yìí láti ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè fi àwọn ìwé ìròyìn náà lọni. Lẹ́yìn náà, ẹ jíròrò àwọn àbá náà láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin.
10 min: Báwo La Ṣe Ṣe Sí? Ìjíròrò. Ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ṣe jàǹfààní nígbà tí wọ́n lo àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà, “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Fi Ìgboyà Sọ̀rọ̀ Nípa Ìjọba Ọlọ́run.” Ní kí àwọn ará sọ àwọn ìṣòro tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Báwo ni wọ́n ṣe borí àwọn ìṣòro yìí?
10 min: Ìròyìn Nípa Ìpolongo Àkànṣe Tá A Ṣe. Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó sọ àsọyé yìí. Ṣe àkópọ̀ àwọn kókó pàtàkì látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù yìí nípa ìdí tó fi yẹ ká túbọ̀ máa polongo Ìjọba Ọlọ́run. Báwo ni ìjọ ṣe tẹ̀ lé ìtọ́ni yìí? Àwọn àṣeyọrí wo lẹ ṣe nígbà tí ẹ̀ ń ṣe ìpolongo náà?
Orin 45 àti Àdúrà