Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní August: Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!, Tẹ́tí sí Ọlọ́run tàbí Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé. September àti October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! November: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? tàbí Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?
◼ Ẹ ṣe àyípadà sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ti ọ̀sẹ̀ tó ṣáájú àpéjọ agbègbè yín kẹ́ ẹ lè fi jíròrò àwọn ìmọ̀ràn àti àwọn ohun tó yẹ ká fi sọ́kàn nípa àpéjọ àgbègbè tó wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí àti lẹ́tà tá a kọ sí gbogbo ìjọ ní August 3, 2013, nípa bá a ṣé lè dènà jàǹbá láwọn ìpàdé wa. Tó bá wá di oṣù kan tàbí méjì lẹ́yìn àpéjọ àgbègbè yín, ẹ lè lo apá tó wà fún ohun tó ń fẹ́ àbójútó láti fi jíròrò àwọn ohun táwọn ará rí pé ó máa wúlò fún àwọn lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ lára àwọn ohun tẹ́ ẹ gbọ́ ní àpéjọ àgbègbè.