Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ October 13
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ OCTOBER 13
Orin 8 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 14 ìpínrọ̀ 10 sí 15 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Diutarónómì 4-6 (10 min.)
No. 1: Diutarónómì 4:29-43 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Kristẹni Gbọ́dọ̀ Gbé Kìkì Kristẹni Níyàwó—td 19E (5 min.)
No. 3: Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Kì Í Fẹ́ Ju Ìyàwó Kan Lọ—td 19Ẹ (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Máa Ṣe Iṣẹ́ Ìwàásù Lọ́nà Tó Fi Hàn Pé Ó Jẹ́ Kánjúkánjú? Àsọyé tó ń tani jí tá a gbé ka 2 Tímótì 4:2. Lo ìsọfúnni tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ March 15, 2012, ojú ìwé 16 àti 17, ìpínrọ̀ 7 sí 9.
10 min: Kí Nìdí Tí Iṣẹ́ Ìwàásù Wa Fi Jẹ́ Kánjúkánjú? Alàgbà ni kó sọ àsọyé yìí. A gbé e ka Ilé Ìṣọ́ March 15, 2012, ojú ìwé 15 àti 16, ìpínrọ̀ 3 sí 6 àti ojú ìwé 17 àti 18, ìpínrọ̀ 14 sí 18. Tẹnu mọ́ bí lílo àwọn àbá tó wà nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa tó ní àkòrí náà, “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I” ṣe lè jẹ́ ká máa wàásù lọ́nà tó fi hàn pé ó jẹ́ kánjúkánjú.
15 min: “Máa Lo Àǹfààní Tó O Bá Ní Láti Tan Ìhìn Rere Ìjọba Náà Kálẹ̀!” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ìpínrọ̀ kẹta, ní kí àwọn ará sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n wàásù lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà. Níparí ọ̀rọ̀ rẹ, so ẹṣin ọ̀rọ̀ oṣù yìí mọ́ iṣẹ́ rẹ, kó o sì rọ àwọn ará pé kí wọ́n ka àpilẹ̀kọ méjèèjì náà, “Ìjíròrò Láàárín Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Ẹnì Kan” èyí tá a máa jíròrò ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀.
Orin 97 àti Àdúrà